Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 30
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 30
Orin 131 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 24 ìpínrọ̀ 10 sí 15 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 21-23 (10 min.)
No. 1: Ìsíkíẹ́lì 23:35-45 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Ìfẹ́ Ọlọ́run Ti Níye Lórí Tó?—Jòh. 3:16; Róòmù 8:38, 39 (5 min.)
No. 3: Ṣíṣe Ayẹyẹ Máàsì Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu—td 28B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 8 láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù August.
25 min: “Bá A Ṣe Lè Kọ́kọ́ Wá Àwọn Èèyàn Ká Tó Wàásù.” Ìbéèrè àti ìdáhùn tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn máa bójú tó. Sọ bí ìsọfúnni yìí ṣe bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu. Bí ìjọ yín bá ń ṣètìlẹ́yìn fún àwùjọ tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè tàbí tí ẹ bá máa ní láti wá àwọn tó ń sọ èdè tẹ́ ẹ fi ń ṣèpàdé, nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, ṣe àṣefihàn ohun tẹ́ ẹ lè sọ tí ẹ bá ń wá àwọn èèyàn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiyín.
Orin 92 àti Àdúrà