ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/96 ojú ìwé 7
  • Bíbójú Tó Àìní Tẹ̀mí Àwọn Adití

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bíbójú Tó Àìní Tẹ̀mí Àwọn Adití
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Ṣìkẹ́ Àwọn Arákùnrin àti Arábìnrin Rẹ Tó Jẹ́ Adití!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àwọn Adití Ń yin Jèhófà
    Jí!—1997
  • Wà Lójúfò Láti Wá Àwọn Adití Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Yín Rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • ‘Jèhófà Ti Mú Kí Ojú Rẹ̀ Tàn sí Wọn Lára’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 9/96 ojú ìwé 7

Bíbójú Tó Àìní Tẹ̀mí Àwọn Adití

1 Iye àwọn adití tí ń pọ̀ sí i ń fà sún mọ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà náà, wọ́n sì ń wá sínú ipò ìbátan oníyàsímímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. (Joh. 10:3, 11) Àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ, pàápàá jù lọ àwọn alàgbà, gbọ́dọ̀ wà lójúfò sí àìní tẹ̀mí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa adití.

2 Kíkojú Àìní Àwọn Adití: A ń ṣètò fún títú àwọn ìpàdé ìjọ sí èdè àwọn adití, níbi tí a bá ti ní àwọn atúmọ̀ tí ó dáńgájíá. Bí kò bá sí ẹnikẹ́ni nínú ìjọ tí ó gbọ́ èdè àwọn adití, ó lè bójú mu láti darí àwọn adití sí ìjọ àdúgbò tí wọ́n ti ń ṣe èyí. Àmọ́ ṣáá ó, bí irú ètò bẹ́ẹ̀ kò bá sí ní àdúgbò yín, ó lè ṣeé ṣe fún àwọn akéde tí a yan iṣẹ́ yìí fún láti jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn adití, kí wọ́n sì máa kọ kókó pàtàkì ohun tí a ń jíròrò fún wọn sórí ìwé.

3 Ìṣètò Àyíká àti Ti Ìjọ: Alábòójútó àyíká ní ń bójú tó ṣíṣe kòkáárí ìṣètò ṣíṣètumọ̀ sí èdè àwọn adití ní àwọn àpéjọ àyíká àti àwọn ọjọ́ àpéjọ àkànṣe. A lè yan alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ó tóótun láti jẹ́ olùṣekòkáárí. A lè yan àwọn arákùnrin àti arábìnrin títóótun, tí wọ́n sì jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, láti ṣàjọpín nínú títúmọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ. A lè tẹ̀ lé ìlànà kan náà nínú ìjọ, ní rírí i dájú pé a bójú tó àìní àwọn adití dáradára.

4 Yóò dára jù lọ láti jẹ́ kí àwọn adití jókòó sí ibi tí yóò ti ṣeé ṣe fún wọn láti máa wo atúmọ̀ àti orí pèpéle ní tààràtà. Èyí ṣe pàtàkì ní àwọn ìpàdé ìjọ àti ní àwọn àpéjọ àyíká. Nínú àwọn ìpàdé ìjọ, yóò dára kí atúmọ̀ náà jókòó, bí àwọn adití tí ó wà níjokòó bá kéré. Bí ó bá ṣeé ṣe, yóò dára kí àwọn alàgbà gba àbá tí ó ṣe gúnmọ́ lọ́dọ̀ arákùnrin adití, tí ó dàgbà dénú, lórí ọ̀nà tí ó dára jù láti to àwọn ìjókòó.

5 Bí ẹ bá ní ẹni tí ó lè túmọ̀ dáradára, tí ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tí iye àwọn arákùnrin àti arábìnrin adití sì pọ̀ tó, àwọn alàgbà lè pinnu pé kí a máa fi èdè àwọn adití darí àwọn ìpàdé kan látòkè délẹ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lè jẹ́ ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tí a fi bẹ̀rẹ̀. Bí ìjọ yóò bá fẹ́ láti fi èdè àwọn adití (tàbí èdè míràn yàtọ̀ sí Gẹ̀ẹ́sì) darí èyíkéyìí lára àwọn ìpàdé márùn-ún ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ ọkàn wọn tó Society létí. Ó dára láti ní in lọ́kàn pé Èdè Àwọn Adití gbogbogbòò ni èdè tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn adití àgbàlagbà ń sọ ní orílẹ̀-èdè yìí.

6 Bí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ láàárín àwọn adití àti àwọn tí ń gbọ́rọ̀ tilẹ̀ lè béèrè fún àkànṣe ìsapá lọ́dọ̀ àwùjọ méjèèjì, ó yẹ kí gbogbo mẹ́ḿbà ìjọ sakun láti di ojúlùmọ̀ ara wọn, kí ojúlówó pàṣípààrọ̀ ìṣírí baà lè wà. (Heb. 10:24) Irú ẹ̀mí yìí láàárín àwọn ará yóò jẹ́ kí gbogbo àwọn ẹni tuntun nímọ̀lára pé a gba àwọn tọwọ́tẹsẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́