Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 10
Orin 46
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù December sílẹ̀. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ December 15 àti Jí! October-December. (Lo àbá kẹta lójú ìwé 8 fún Jí! October-December.)
20 min: Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2008. Àsọyé tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sọ. Lo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2007 láti fi jíròrò àwọn kókó tó bá ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ yín. Ṣàlàyé ojúṣe olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Fún àwọn ará níṣìírí láti máa fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tá a bá yàn fún wọn, kí wọ́n máa lóhùn sí Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, kí wọ́n sì máa fàwọn àbá tí wọ́n bá ń rí gbà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ látinú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílò.
15 min: “Máa Sọ̀rọ̀ Ìtùnú Fáwọn Tó Sorí Kọ́.”a Sọ ìrírí ṣókí kan tàbí méjì.
Orin 34
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 17
Orin 28
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò “Àpéjọ Àyíká Tó Ń Bọ̀ Lọ́nà.” Sọ ọjọ́ tí àpéjọ àyíká náà máa bọ́ sí fáwọn ará, bẹ́ ẹ bá mọ̀ ọ́n. Ní kí àwọn tó wà láwùjọ wo fídíò wa tuntun tó dá lórí bí Jèhófà ṣe ń kó àwa èèyàn rẹ̀ jọ láti máa wàásù ìhìn rere, ìyẹn Jehovah’s Witnesses—Organized to Share the Good News. Èyí á jẹ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ìjíròrò tó máa wáyé lórí fídíò náà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tá a máa ṣe ní ọ̀sẹ̀ December 31.
15 min: “Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Iná Ìtara Yín fún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Jó Rẹ̀yìn.”b Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó máa ń fìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Àwọn ìbéèrè tó o máa bi í: Ọgbọ́n wo lo dá sí i tí ìtara rẹ ò fi dín kù? Kí ló ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí iná ìtara rẹ ò fi jó rẹ̀yìn?
20 min: “Máa Fáwọn Èèyàn Ní Ìwé Ìròyìn Tó Ń Jẹ́rìí sí Òtítọ́.”c Ní káwọn ará sọ̀rọ̀ lórí àpilẹ̀kọ tó wà ní ojú ìwé 4 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2006. Sọ pé kí wọ́n ka Ilé Ìṣọ́ January 1 àti Jí! January-March, kí wọ́n sì mú un dání wá sípàdé lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀.
Orin 139
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 24
Orin 212
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Sọ ìwé tá a máa lò lóṣù January, kó o sì ṣe àṣefihàn kan tó bá ìwé ìròyìn náà mu.
15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Fi Ìwé Ìròyìn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé Lọni. Gbé ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ yìí karí Ilé Ìṣọ́ January 1 àti Jí! January-March. Lẹ́yìn tó o bá ti ṣe àkópọ̀ ṣókí nípa ohun tó wà nínú ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan, ní kí àwùjọ sọ àwọn àpilẹ̀kọ tó máa fa àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín lọ́kàn mọ́ra jù lọ, kí wọ́n sì tún sọ ìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀. Ní kí àwùjọ sọ bí wọ́n ṣe fẹ́ gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lóde ẹ̀rí nípa lílo díẹ̀ lára àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ní lọ́kàn. Ìbéèrè wo lèèyàn lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo lèèyàn lè kà nínú àpilẹ̀kọ náà? Báwo lèèyàn ṣe lè ṣàlàyé bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe bá àpilẹ̀kọ náà mu? Lo àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a dábàá nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tàbí ọ̀kan tí àwùjọ dámọ̀ràn láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan lọni.
20 min: “Fi Dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ṣe Àfojúsùn Rẹ.”d Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tàbí àwọn méjì tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Báwo ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà? Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú sí?
Orin 21
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 31
Orin 89
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù December sílẹ̀.
15 min: Fífọkàn Sin Ọlọ́run Ní Agbára Tí Ń Súnni Ṣiṣẹ́. Ọ̀rọ̀ tí ń fúnni níṣìírí tá a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, March 1, 1990, ojú ìwé 22 sí 23.
25 min: “Iṣẹ́ Ìwàásù Tó Lókìkí Tó Báyìí Ò Tíì Wáyé Rí!”e Ní káwọn ará sọ̀rọ̀ lórí báwọn ìbátan, àwọn ojúlùmọ̀, ìpadàbẹ̀wò, àtàwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe fọkàn rere gba ohun tó wà nínú fídíò Jehovah’s Witnesses—Organized to Share the Good News, nígbà tí wọ́n fi hàn wọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí àfidípò, jíròrò “Ìfẹ́ Tí Wọ́n Ní sí Ọlọ́run Ló Mú Kí Wọ́n Wà Níṣọ̀kan” látinú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2005, ojú ìwé 4 sí 6.
Orin 202
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 7
Orin 100
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò “Àpéjọ Àkànṣe Tó Ń Bọ̀ Lọ́nà,” kó o sì sọ ọjọ́ tó máa bọ́ sí, bẹ́ ẹ bá mọ̀ ọ́n.
15 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé àti ìjíròrò tí alàgbà máa bójú tó. Jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá ò fa ọ̀rọ̀ wọn yọ, bí àkókò bá ṣe wà sí.
20 min: “Bí Ìdílé Ṣe Lè Jọ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”f Bó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, ní kí olórí ìdílé kan tàbí méjì sọ àkókò àti ọjọ́ tí wọ́n rí i pé ó rọrùn fáwọn láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
Orin 164
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
f Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.