Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 14
Orin 183
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù April sílẹ̀. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ April 1 àti Jí! April-June (Lo àbá kẹta lójú ìwé 8 fún Jí! April-June.)
15 min: ‘Ẹ Fi Ara Yín Hàn Ní Ẹni Tó Kún fún Ọpẹ́.’a Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.
20 min: “Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú.”b Ní kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí tó gbámúṣé tí wọ́n ní tó fi hàn pé àǹfààní wà nínú títu ẹnì kan tó ń ṣòfò nínú.
Orin 42
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 21
Orin 171
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n mú Ilé Ìṣọ́ May 1 àti Jí! April-June wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, kí wọ́n sì múra sílẹ̀ láti ṣàlàyé àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó máa bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: Ronú Lọ́nà Tó Ṣe Tààrà Kó O sì Fi Ọgbọ́n Hùwà. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ July 15, 2003, ojú ìwé 21 sí 23. Alàgbà tó nírìírí ni kó bójú tó o.
Orin 132
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 28
Orin 55
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù April sílẹ̀. Sọ̀rọ̀ ṣókí lórí Ilé Ìṣọ́ May 1 àti Jí! April-June, kó o wá ní káwọn ará sọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀. Ní kí wọ́n dábàá àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó bá àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò mu. Ìbéèrè wo ni wọ́n lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wọ́n máa fẹ́ láti kà látinú àpilẹ̀kọ náà? Báwo ni wọ́n ṣe máa fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ti ìdáhùn wọn lẹ́yìn? Lo ọ̀kan lára àwọn àbá tí àwùjọ dámọ̀ràn tàbí èyí tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. (O lè lo àbá kẹrin lójú ìwé 8 fún Jí! April-June.)
30 min: “Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2008 ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”c Akọ̀wé ìjọ ni kó bójú tó o. Kó o tó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò yìí, ka lẹ́tà tá a kọ ní March 1, 2008, èyí tá a fi sọ déètì àpéjọ àgbègbè tá a yan ìjọ yín sí. Tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 8, ka gbogbo kókó tó wà nínú àpótí náà, “Bó O Ṣe Lè Béèrè fún Ilé Tó O Máa Dé Sí.” Gba àwọn ará níyànjú láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò tó bá yẹ, kó tó pẹ́ jù.
Orin 99
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 5
Orin 217
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: Jèhófà Kì Yóò Fi Ọ́ Sílẹ̀ Lọ́nàkọnà. Àsọyé tó ń gbéni ró tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ October 15, 2005, ojú ìwé 8 sí 11.
20 min: “Máa Tẹ̀ Síwájú Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́.”d Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, fi àlàyé kún un látinú ìwé Jàǹfààní ojú ìwé 6 sí 8, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Bí O Ṣe Lè Jàǹfààní ní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”
Orin 11
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.