ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/08 ojú ìwé 2-3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 5/08 ojú ìwé 2-3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé tá a ó lò lóṣù May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ sapá lákànṣe láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fìfẹ́ hàn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n sì tún wá gbọ́ àkànṣe àsọyé àmọ́ tí wọn kì í wá sípàdé ìjọ déédéé. Ìdí tẹ́ ẹ fi fẹ́ padà bẹ̀ wọ́n wò ni láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. June: Ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Ẹmi Awọn Oku-Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun-Ṣé O Ti Rí I? àti “Sáwo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.”

◼ Kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà jíròrò lẹ́tà July 6, 2006, èyí tó sọ nípa bí wọ́n ṣe lè múra sílẹ̀ de àjálù, kí wọ́n sì rí i pé àdírẹ́sì ibi tí akéde kọ̀ọ̀kan ń gbé wà lọ́wọ́ àwọn. Láwọn àdúgbò tí àjálù ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀, kẹ́ ẹ rí i pé ẹ béèrè ọ̀nà míì tẹ́ ẹ lè gbà kàn sí wọn bí ọ̀ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀. Bákan náà, yàtọ̀ sí ọ̀ràn pàjáwìrì, ó tún máa ń dáa táwọn akéde bá lè máa fi tó alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wọn tàbí alàgbà míì létí tí wọ́n bá fẹ́ rìnrìn àjò fún àkókò gígùn, bóyá lásìkò tí wọ́n bá gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, tí wọ́n bá wà ní ilé ìwòsàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:

“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”—Faransé, Gẹ̀ẹ́sì, Ìgbò àti Yorùbá

Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!—Ìṣẹ̀kírì

Ṣé Kádàrá Ló Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ? (Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Nọ́ńbà 81)—Àbúà, Ẹdó, Ẹ́fíìkì, Gẹ̀ẹ́sì, Gòkánà, Haúsá, Ìgbò, Ísókó, Ìṣẹ̀kírì, Kánà, Tífí, Ùròbò, Yorùbá

Ta Ni Jésù Kristi? (Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Nọ́ńbà 24)—Ẹ́fíìkì, Haúsá, Ìgbò, Ísókó, Tífí, Yorùbá

Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn—Ìgbò

Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (ẹ̀dà tó léèpo ẹ̀yìn líle àti ẹ̀dà tó léèpo ẹ̀yìn rírọ̀)—Ìgbò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́