Jàǹfààní Látinú Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
1 Láìpẹ́ yìí, olórí ìdílé kan ní kí alàgbà kan jọ̀wọ́ sọ ohun tóun lè lò láti kọ́ ọmọ òun pé irọ́ pípa ò dáa. Alàgbà yẹn ní kó lọ ka orí 22 nínú ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Ṣé ẹ̀yin olórí ìdílé mọ àǹfààní tó wà nínú lílo ìwé yìí? A ṣe é láti kọ́ àwọn ọmọdé níwà ọmọlúwàbí. Láfikún sí bí ìwé yìí ṣe kọ́ àwọn ọmọdé pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣohun tí kò dára, ó tún ṣàlàyé àwọn òtítọ́ Bíbélì àti bí wọn ò ṣe ní lọ́wọ́ sáwọn ohun tí kò dáa tó kúnnú ayé búburú yìí.
2 Ó dájú pé gbogbo àwọn ọmọ wa ló máa jàǹfààní nínú ìwé yìí. Bí ẹ̀yin òbí ò bá tíì parí kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, ẹ ò ṣe kúkú ṣètò láti máa fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín. Lẹ́yìn tó o bá parí kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí pẹ̀lú ìdílé rẹ, wàá lè mọ bó o ṣe lè túbọ̀ lo àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ẹ̀ lọ́kan-ò-jọ̀kan láti bójú tó ìṣòro tó bá jẹ yọ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ.
3 Lẹ́yìn tí Mósè ti sọ ọ̀pọ̀ lára òfin Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ.” (Diu. 6:6, 7) Bó o bá ń lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ lọ́nà tó múná dóko, ìgbà yẹn lo tó pa àṣẹ ọlọ́gbọ́n yìí mọ́. Àwọn ìbéèrè tá a fi sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó o bá ń fi ìwé yìí kọ́ àwọn ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́. Jọ̀wọ́ fi ìbéèrè yìí sínú ìwé náà kó o bàa lè máa rí i lò nígbà tẹ́ ẹ bá ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú rẹ̀.