Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 14
Orin 126
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù July sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ July 1 àti Jí! July–September. (Lo abá kẹta lójú ìwé 4 fún Jí! July–September.)
15 min: Ǹjẹ́ O Ní “Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ”? Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ May 15, 2006, ojú ìwé 13 sí 16. Tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa fìgboyà wàásù.
20 min: “Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn.”a Sọ àwọn nǹkan tó mú kí ìwé yìí yàtọ̀. Sọ̀rọ̀ lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti ìtọ́ni tó wà lójú ìwé 3 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí. Gba àwọn ará níyànjú láti máa pésẹ̀ déédéé kí wọ́n sì máa dáhùn fàlàlà. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n máa ń múra ibi tá a fẹ́ kà sílẹ̀ dáadáa, ní kí wọ́n sọ ohun tó mú kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀.
Orin 147
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 21
Orin 95
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ fún àwọn ará pé kí wọ́n mú Ilé Ìṣọ́ August 1 àti Jí! July–September wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, kí wọ́n sì múra sílẹ̀ láti ṣàlàyé àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó máa bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: “Ìmúrasílẹ̀—Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò Tó Múná Dóko.”b Fi ìdánìkansọ̀rọ̀ oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́rin kún un níbi tí akéde kan ti ń múra ìpadàbẹ̀wò tó fẹ́ lọ ṣe. Ó wo àkọsílẹ̀ rẹ̀, ó sì pinnu pé òun ní láti bẹ ẹni méjì wò lópin ọ̀sẹ̀ yìí. Lẹ́yìn náà ló wá ronú lórí ohun tó ti bá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jíròrò tẹ́lẹ̀, ó pinnu ohun tó fẹ́ kí wọ́n mọ̀ báyìí, ó sì múra bó ṣe máa ṣe é láṣeyọrí. Ó múra bó ṣe máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan. Ó sì múra bó ṣe máa mú kí ìfẹ́ ẹnì kejì pọ̀ sí i nípa lílo àbá tó wà ní ìpínrọ̀ 5.
Orin 189
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 28
Orin 6
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù July sílẹ̀. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Sọ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò lóṣù August, kó o sì ṣàṣefihàn bá a ṣe lè lo ọ̀kan nínú wọn.
15 min: Bá A Ṣe Lè Máa Fi Sọ́kàn Pé Ọjọ́ Jèhófà Ti Sún Mọ́lé Gan-an. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ December 15, 2006, ojú ìwé 18 sí 19, ìpínrọ̀ 17 sí 21, kí ẹni tó bá ṣiṣẹ́ yìí fi ìtara sọ ọ́.
20 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Tó Bá Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ ṣókí lórí Ilé Ìṣọ́ August 1 àti Jí! July–September, ní káwọn ará sọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀. Ní kí wọ́n mẹ́nu ba àwọn kókó kan látinú àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò lóde ẹ̀rí. Ìbéèrè wo ni wọ́n lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wọ́n máa fẹ́ láti kà látinú àpilẹ̀kọ náà? Lo àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a dábàá nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tàbí ọ̀kan tí àwùjọ dámọ̀ràn láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan. (O lè lo àbá kẹrin lójú ìwé 4 fún Jí! July-September.)
Orin 106
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 4
Orin 222
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: Ṣé Àwọn Ọmọ Rẹ Ń Gbára Dì Láti Borí Àwọn Ìṣòro Tí Wọ́n Ń Kojú Nílé Ìwé? Sọ ọ́ bí àsọyé kó o sì jẹ́ kí àwùjọ dá sí i. Mẹ́nu ba àwọn ìṣòro kan táwọn Kristẹni ọ̀dọ́ ń kojú nílé ìwé. Ṣàlàyé báwọn òbí àtàwọn ọmọ ṣe lè fi ìwé Watch Tower Publications Index wá àlàyé tó wúlò lórí àwọn ọ̀ràn yìí. Mú àwọn àpẹẹrẹ bíi mélòó kan wá. (Wo àkòrí náà “Schools,” kó o wá wo ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ náà “experiences” lábẹ́ rẹ̀.) Ní káwọn tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú ìdílé Kristẹni sọ báwọn òbí wọn ṣe múra wọn sílẹ̀ de ìṣòro, tí wọ́n sì fàwọn ìlànà Bíbélì sílò níléèwé. Wọ́n tún lè sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ṣe fi àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n rí nínú Jí! múra iṣẹ́ ilé ìwé kan sílẹ̀. Ní kí wọ́n sọ bí wíwàásù fáwọn ọmọ ilé ìwé wọn ṣe jẹ́ ààbò fún wọn.
20 min: “À Ń Dojú Àwọn Nǹkan Tó Fìdí Múlẹ̀ Gbọin-in Gbọin-in Dé.”c Ní kí àwùjọ sọ bí ẹni tó ṣèkẹ́kọ̀ọ́ wọn ṣe fi sùúrù ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n gbà gbọ́ sílẹ̀.
Orin 83
[Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.