Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò lóṣù September: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́jọ́ tẹ́ ẹ bá kọ́kọ́ bá onílé sọ̀rọ̀. Tí onílé bá sì ti ní ìwé yìí, ẹ fi bó ṣe lè jàǹfààní látinú rẹ̀ hàn án nípa jíjẹ́ kó mọ bá a ṣe ń fìwé náà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bí ẹni náà bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa, ẹ jíròrò ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? pẹ̀lú rẹ̀, kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. December: Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí la máa lò. Bí onílé bá ní ọmọ, fún un ní ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà.
◼ Níwọ̀n bí oṣù November ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù yẹn.
◼ Ọ̀sẹ̀ April 20, 2009 la máa sọ àkànṣe àsọyé tó máa ń wáyé lásìkò Ìrántí Ikú Kristi. A máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ àkòrí àsọyé náà nígbà tó bá yá. Káwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká tàbí àpéjọ lópin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé náà lọ́sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àkànṣe àsọyé yìí ṣáájú April 20.
◼ Kí ẹni tí alága àwọn alábòójútó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ fún oṣù June, July, àti August. Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kan náà ṣe àyẹ̀wò yìí tẹ̀ léra o. Bó bá ti parí àyẹ̀wò náà, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó lóṣù tó ń bọ̀.—Ẹ wo ìwé tó ṣàlàyé nípa bó ṣe yẹ ká bójú tó àkáǹtì ìjọ, ìyẹn Instructions for Congregation Accounting (S-27).
◼ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má gbàgbé pé Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ló gbọ́dọ̀ máa buwọ́ lu lẹ́tà tẹ́ ẹ bá fi ń sọ̀rọ̀ nípa akéde tó bá kúrò nínú ìjọ yín lọ sí ìjọ míì, kì í ṣe akọ̀wé nìkan. Ìlànà yìí ni kẹ́ ẹ máa lò fún gbogbo akéde, yálà ẹni náà ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ tàbí kò ní in. Kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn tó buwọ́ lu lẹ́tà tí wọ́n fi ń sọ̀rọ̀ nípa akéde tó bá ń lọ sí ìjọ míì, kí wọ́n rí i dájú pé àwọn nǹkan mẹ́ta tó ṣe pàtàkì yìí wà nínú rẹ̀: (1) déètì tí wọ́n kọ lẹ́tà náà, (2) orúkọ àti àdírẹ́sì ìjọ wọn ní kíkún àti (3) orúkọ àti àdírẹ́sì ìjọ tuntun tí akéde náà ń lọ ní kíkún.
◼ Káwọn alàgbà má gbàgbé láti fi fọ́ọ̀mù Kingdom Hall Maintenance/Safety Checklist (CN-14), ṣàyẹ̀wò Gbọ̀ngàn Ìjọba, bí wọ́n ṣe máa ń ṣe lọ́dọọdún. Kí wọ́n bàa lè ṣe àyẹ̀wò yìí bó ṣe yẹ, kí wọ́n tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú lẹ́tà August 1, 2007, tá a kọ sí gbogbo ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Lẹ́yìn àyẹ̀wò náà, kí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú fọ́ọ̀mù yìí, kí wọ́n buwọ́ lù ú, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó pẹ́ tán ní September 30.
◼ Fún àǹfààní àwọn akéde àtàwọn tó nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa tó jẹ́ afọ́jú àtàwọn tí kò ríran dáadáa tí wọ́n máa ń ka ìwé àwọn afọ́jú, ìyẹn Braille tàbí tí wọ́n ní kọ̀ǹpútà tó lè ka ọ̀rọ̀ téèyàn bá tẹ̀ sórí ẹ̀ jáde, ètò ti wà báyìí láti máa fi ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ táwọn afọ́jú lè kà ránṣẹ́ sí wọn látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì fún lílò tara wọn. Àwọn tó wà nílẹ̀ ni ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá à ń lò lóde ẹ̀rí àti ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ní Grade 2 English Braille àti ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ní Grade 1 French Braille àti Grade 1 Spanish Braille. Orí ibi táwọn tó bá béèrè fún un ti máa ń gba lẹ́tà, ìyẹn e-mail, lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, la máa fi ránṣẹ́ sí. Káwọn tó bá fẹ́ gba ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fáwọn afọ́jú yìí sọ fún akọ̀wé ìjọ wọn pé kó bá wọn fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí P.M.B. 1090, Benin City, 300001, Edo State. Kí akọ̀wé kọ “Attention: Braille Desk” sẹ́yìn àpò ìwé tó bá fi fi lẹ́tà náà ránṣẹ́. Àwọn nǹkan tí akọ̀wé máa kọ sínú lẹ́tà náà ni orúkọ àti àdírẹ́sì ẹni tó fẹ́ gba ìwé náà, orúkọ tàbí irú ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ tẹ́ni náà ń lò, àdírẹ́sì e-mail tó ń lò, àti oríṣi èdè Braille tó lè kà, bóyá ti Gẹ̀ẹ́sì, Sípáníìṣì tàbí Faransé. Tẹ́ni náà ò bá ní e-mail, ó lè lo àdírẹ́sì e-mail ẹlòmíì tó lè máa gba àwọn ìsọfúnni náà tá á sì fi ránṣẹ́ sórí kọ̀ǹpútà tiẹ̀.
◼ Àwọn Àwo CD àti DVD Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:
Àwọn Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì—Lórí MP3 (Oríṣi àwòkẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìnlá lórí àwo kan ṣoṣo)—Gẹ̀ẹ́sì
Pursue Goals That Honor God (Lórí àwo DVD)—Gẹ̀ẹ́sì
To the Ends of the Earth àti United by Divine Teaching (Lórí àwo DVD)—Faransé, German, Gẹ̀ẹ́sì, Italian, Japanese, Portuguese àti Sípáníìṣì
Watchtower Library—Ẹ̀dà ti ọdún 2007 (Lórí CD-ROM)—Gẹ̀ẹ́sì
Young People Ask—How Can I Make Real Friends? (Lórí àwo DVD)—Faransé, German, Gẹ̀ẹ́sì, Italian, Japanese, Portuguese, Russian àti Sípáníìṣì