ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/08 ojú ìwé 6
  • Ojú Táwa Kristẹni Fi Ń Wo Ṣíṣe Èrú Nígbà Ìdánwò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ojú Táwa Kristẹni Fi Ń Wo Ṣíṣe Èrú Nígbà Ìdánwò
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 9/08 ojú ìwé 6

Ojú Táwa Kristẹni Fi Ń Wo Ṣíṣe Èrú Nígbà Ìdánwò

1 Gbogbo àwa Kristẹni tòótọ́ la ní irú èrò tí Pọ́ọ̀lù ní, bó ṣe wà nínú Hébérù 13:18 pé: “A ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” Bá a tiẹ̀ ń gbé nínú ayé tí ìwà ìbàjẹ́ ti túbọ̀ ń peléke sí i lójoojúmọ́ yìí, èrò wa ò yàtọ̀ sí ti Pọ́ọ̀lù. Kò síbi tí ìwà ìbàjẹ́ ò sí láyé tá a wà yìí, kódà àwọn ọmọléèwé kì í ṣòótọ́ mọ́ nígbà ìdánwò. Ọ̀pọ̀ ló fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó bá gbà kí wọ́n lè yege nínú ìdánwò torí àtirí ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ tàbí torí àtirí iléèwé gíga wọ̀, ìyẹn ló sì máa ń sún wọn dédìí ṣíṣe èrú nígbà ìdánwò.

2 Bí Wọ́n Ṣe Ń Ṣe É: Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn èèyàn gbà ń ṣèrú nígbà ìdánwò kí wọ́n ṣáà lè yege. Wọ́n máa ń mú ìwé pélébé tí wọ́n ti kọ ìdáhùn sí wọnú ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣèdánwò, wọ́n máa ń jí ẹni tó bá jókòó tì wọ́n wò, wọ́n máa ń ra ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó máa jáde ṣáájú ọjọ́ ìdánwò, wọ́n máa ń fi tẹlifóònù alágbèéká wọn gba ìdáhùn nígbà ìdánwò, tàbí kí wọ́n ti kọ ìdáhùn síbi kọ́lọ́fín ara kí wọ́n tó wọlé. Àwọn míì sì máa ń sanwó fáwọn kan láti bá wọn ṣe ìdánwò.

3 Wọ́n tún ti wá fi ọ̀nà míì kún un báyìí. Àwọn ọ̀gá iléèwé kan máa ń gba àfikún owó lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìdánwò. Wọ́n á wá fún àwọn tó bá san àfikún owó náà ní káàdì tí wọ́n máa fi wọnú gbọ̀ngàn tí wọ́n ti máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìdánwò. Ìròyìn ti tó wa létí pé àwọn òbí kan máa ń fẹ́ káwọn ọmọ wọn lọ ṣèdánwò láwọn iléèwé tí wọ́n ti máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìdánwò. Àwọn ọ̀dọ́ kan sì máa ń tọ́jú owó kí wọ́n bàa lè sanwó fáwọn tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìdánwò láìjẹ́ káwọn òbí wọn mọ̀ nípa ẹ̀.

4 Nígbà míì, ńṣe làwọn ọ̀gá iléèwé kan máa ń fipá mú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọ́n san àfikún owó kí wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìdánwò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀gá iléèwé kan halẹ̀ mọ́ arábìnrin kan pé bí kò bá san àfikún owó náà, àwọn ò ní jẹ́ kó ṣèdánwò. Ẹ̀gbọ́n arábìnrin yìí, tó jẹ́ alàgbà nínú ìjọ, kọ lẹ́tà sí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀kọ́ nípa ọ̀ràn náà. Ìyẹn sì mú kí wọ́n fàṣẹ ọba mú àwọn kan lára àwọn ọ̀gá iléèwé tó wà nídìí ọ̀ràn náà. Òótọ́ tó wà nínú ọ̀ràn náà ni pé Ilé Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀kọ́ àti ìjọba orílẹ̀-èdè yìí ò fọwọ́ sí ìwà àìṣòótọ́ yìí lọ́nàkọnà. Àmọ́ àwọn ọ̀gá iléèwé àtàwọn olùkọ́ kan ló wà nídìí ìwàkiwà yìí torí wọ́n ń rí tiwọn jẹ níbẹ̀, wọ́n sì ti wá di gbajúmọ̀ torí wọ́n ti ran ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti rí èsì ìdánwò tó yanranntí gbà.

5 Ìdí Tá Ò Fi Gbọ́dọ̀ Dárú Ẹ̀ Láṣà: Bíbélì ò fọwọ́ sí ìwà ìrẹ́nijẹ, ìyẹn sì kan onírúurú ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń hùwà àìṣòótọ́ nígbà ìdánwò. Òwe 11:1 sọ pé: “Òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì tí a fi ń rẹ́ni jẹ jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” Bí ẹnì kan bá ṣèrú kó lè rọ́wọ́ mú nínú ìdánwò, máàkì tó bá gbà tàbí ohun tí èsì ìdánwò náà bá sọ nípa onítọ̀hún ò lè jóòótọ́. Níwọ̀n bí Jèhófà sì ti kórìíra irú ìwà màgòmágó bẹ́ẹ̀, àwa Kristẹni tòótọ́ ò gbọ́dọ̀ dárú ẹ̀ láṣà.

6 Ìdí táwa Kristẹni ò tún fi gbọ́dọ̀ máa ṣèrú lọ́nà èyíkéyìí nígbà ìdánwò ni pé, irú ìwà bẹ́ẹ̀ ò fọ̀wọ̀ hàn fún Késárì. Òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ pé ìjìyà wà fẹ́ni tó bá dárú ẹ̀ láṣà torí ẹ̀wọ̀n lonítọ̀hún ń lọ. Kì í ṣe torí pé a ò fẹ́ ṣẹ̀wọ̀n la ò ṣe ní báwọn dáṣà yìí àmọ́ àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún wa pé ká “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga” la fẹ́ tẹ̀ lé.—Róòmù 13:1-7.

7 Yàtọ̀ síyẹn, àwa Kristẹni kì í ṣèrú nígbà ìdánwò bẹ́ẹ̀ la kì í gba àwọn èèyàn níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé àṣà yìí lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn wa. Jèhófà dá ẹ̀rí ọkàn mọ́ wa kó lè máa kìlọ̀ fún wa nígbàkigbà tá a bá fẹ́ ṣe ohun tí kò dáa. Tá ò bá lọ tẹ́tí sí ẹ̀rí ọkàn wa nínú àwọn ọ̀ràn tó dà bíi pé kò tó nǹkan, ó lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tó burú jáì ká sì wá tipa bẹ́ẹ̀ ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́.—1 Pét. 3:16.

8 Ojúṣe Àwọn Òbí: Kò sí àníàní pé àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń fẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí. Síbẹ̀ àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ̀ pé ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí jẹ àwọn lógún ju ohun yòówù kí wọ́n dà nínú ayé lọ. Àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run mọ̀ pé ìkáwọ́ àwọn ni Jèhófà fi títọ́ àwọn ọmọ sí. (Éfé. 6:4) Torí náà, wọn ò ní fọwọ́ sí i pé káwọn ọmọ wọn hùwàkiwà. Àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn máa ń wáyè láti fi ìṣòtítọ́ àti ìwà ọmọlúwàbí kọ́ wọn.

9 Ibi gbogbo ni wọ́n ti mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí olóòótọ́ èèyàn, kò sì yẹ kí ẹnikẹ́ni nínú wa ṣe ohunkóhun tó máa ba orúkọ rere tá a ní yìí jẹ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká gba àwọn ọ̀dọ́ wa níyànjú láti máa kàwé dáadáa kí wọ́n bàa lè ṣàṣeyọrí níléèwé. (Òwe 10:4; 22:29) Láìka bí ìwà àìṣòótọ́ nígbà ìdánwò ṣe kúnnú ayé sí, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa sapá láti ní ẹ̀rí ọkàn rere níwájú gbogbo èèyàn, ká bàa lè tipa bẹ́ẹ̀ fìyìn fún Jèhófà.—Héb. 13:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́