Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tó wà nísàlẹ̀ yìí la óò gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 27, 2008. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ September 1 sí October 27, 2008, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sì darí rẹ̀ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú.
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Báwo la ṣe lè mọ ìdí táwọn èèyàn fi gba ohun kan gbọ́? [be-YR ojú ìwé 259 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
2. Báwo la ṣe lè mú kẹ́nì kan mú ìkórìíra àti ẹ̀tanú kúrò lọ́kàn rẹ̀? [be-YR ojú ìwé 260 ìpínrọ̀ 2]
3. Báwo la ṣe lè mú káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹ ọkàn wọn wò kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà lè túbọ̀ dán mọ́rán sí i? [be-YR ojú ìwé 261 ìpínrọ̀ 2]
4. Kí la gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn bá a ṣe ń sapá láti dénú ọkàn àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́? [be-YR ojú ìwé 262 ìpínrọ̀ 4]
5. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fiyè sí bá a ṣe ń lo àkókò láwọn ìpàdé ìjọ? [be-YR ojú ìwé 263 ìpínrọ̀ 1, 3, àpótí]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sáwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì? [w90-YR 9/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 3]
7. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sáwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì? [w90-YR 9/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 2]
8. Àwọn àǹfààní wo la lè rí látinú ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù kọ sínú lẹ́tà kejì sáwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì? [w90-YR 9/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 4]
9. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará tó wà ní Fílípì? [w90-YR 11/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 7]
10. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ kọ sáwọn ará tó wà ní Tẹsalóníkà? [w91-YR 1/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 8]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Kí ló túmọ̀ sí láti “fi [ẹni burúkú] lé Sátánì lọ́wọ́ fún ìparun ẹran ara, kí a bàa lè gba ẹ̀mí là”? (1 Kọ́r. 5:5) [w08-YR 7/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú ìwé Kọ́ríńtì Kìíní àti Ìkejì”]
12. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn pẹ̀lú gbólóhùn náà “nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ ìṣù búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí,” “títí” dìgbà wo ló sì ń sọ? (1 Kọ́r. 11:26) [w08-YR 7/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú ìwé Kọ́ríńtì Kìíní àti Ìkejì”]
13. Ìran wo ló wà nínú 2 Kọ́ríńtì 12:2-4, ta ló sì ṣeé ṣe kó rí ìran ọ̀hún? [w04-YR 10/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 4 àti ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 9]
14. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé Òfin Mósè dà bí “akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi”? (Gál. 3:24) [w08-YR 3/1 ojú ìwé 18 sí 21]
15. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó gbàdúrà pé “kí a pa ẹ̀mí àti ọkàn àti ara ẹ̀yin ará mọ́”? (1 Tẹs. 5:23) [w08-YR 9/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Tẹsalóníkà Kìíní àti Ìkejì àti Tímótì Kìíní àti Ìkejì”]