Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò lóṣù October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bí ẹni náà bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa, ẹ jíròrò ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? pẹ̀lú rẹ̀, kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. December: Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí la máa lò. Bí onílé bá ní ọmọ, fún un ní ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. January: Ẹ lè lo ìwé èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ìwé míì tẹ́ ẹ tún lè lò bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà.
◼ Àkíyèsí fún alága àwọn alábòójútó àtàwọn alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run: Ọ̀sẹ̀ December 29, 2008 la máa bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé ọ̀nà tuntun tí a ó máa gbà ṣèpàdé, ẹ máa rí àtúnṣe yìí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tí oṣù December 2008. Nígbà tí alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run bá ń darí Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ yẹn, kó rí i dájú pé òun tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni nípa Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ ìjọba Ọlọ́run tó wà nínú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2009. A kò ní sọ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ lọ́jọ́ náà.
◼ A máa jíròrò fídíò No Blood—Medicine Meets the Challenge ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kan lóṣù January. Bó bá pọn dandan, ẹ lè béèrè fún ẹ̀dà fídíò yìí nípasẹ̀ ìjọ láìjáfara.
◼ Níwọ̀n bí oṣù November ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí ni “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2009.” Ẹ tọ́jú rẹ̀ kẹ́ ẹ lè rí i lò jálẹ̀ ọdún.