ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/08 ojú ìwé 3-6
  • Kíkọ́ Àwọn Ibi Ìjọsìn Lọ́nà Tó Mọ Níwọ̀n Ń Fìyìn fún Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkọ́ Àwọn Ibi Ìjọsìn Lọ́nà Tó Mọ Níwọ̀n Ń Fìyìn fún Jèhófà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àwọn Ibi Ìpàdé Tá A Kọ́ Lọ́nà Tó Mọ Níwọ̀n
  • Ṣíṣe Nǹkan Lọ́nà Tó Mọ Níwọ̀n Ń Sèso Rere
  • Ṣíṣètìlẹyìn Fáwọn Ibi Ìjọsìn Wa Tó Mọ Níwọ̀n
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 11/08 ojú ìwé 3-6

Kíkọ́ Àwọn Ibi Ìjọsìn Lọ́nà Tó Mọ Níwọ̀n Ń Fìyìn fún Jèhófà

1, 2. (a) Kí làwọn èèyàn Ọlọ́run ti ṣe láti bójú tó ìbísí tó ń wáyé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?

1 Nítorí ìbísí ńláǹlà tó ń wáyé nínú ètò Jèhófà lákòókò ìkórè tá a wà yìí, ó pọn dandan pé káwa èèyàn Jèhófà mú àwọn ọ̀nà tá à ń gbà ṣe nǹkan rọrùn. Ká bàa lè bójú tó ìbísí tí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀, láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ti mú kí ọ̀nà tá a gbà ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, pípín wọn kiri, ṣíṣètò àwọn àpèjọ àyíká, àkànṣe àti àgbègbè àti bá a ṣe ń náwó sórí àwọn ibi ìpàdé wa mọ níwọ̀n. (Aísá. 54:1-4; 60:22) Bákan náà, àyípadà ti bá ọ̀nà tá a gbà ń kọ́ àwọn ibi ìjọsìn wa àti bá a ṣe ń lò wọ́n, ká lè bójú tó ìbísí náà.

2 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ibi tá a ti ń ṣe àwọn àpèjọ tó lé ní mẹ́rìnlélógún [24] (àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ṣe é lò fún àpèjọ àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpèjọ) la ti kọ́ jákèjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ipa wo ni ṣíṣe nǹkan lọ́nà tó mọ níwọ̀n kó nínú gbogbo èyí? Àwọn nǹkan wo la ti ṣe lọ́nà tó mọ níwọ̀n láwọn ibi ìjọsìn yìí? Báwo la ṣe lè máa ṣètìlẹ́yìn fáwọn ibi ìpàdé tá a kọ́ lọ́nà tó mọ níwọ̀n yìí?

Àwọn Ibi Ìpàdé Tá A Kọ́ Lọ́nà Tó Mọ Níwọ̀n

3. Àwọn ọ̀nà tó rọrùn wo la gbà ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba báyìí?

3 Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba: Ìdí pàtàkì tá a fi ṣètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ò ti fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ bíi Nàìjíríà ni pé, ká bàa lè kúnjú àìní náà láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó pọ̀ sí i. Kó lè ṣeé ṣe fún wa láti tètè máa kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba náà parí, ètò Ọlọ́run ti ní àwọn ìlànà kan tá a ó máa tẹ̀ lé. Lórílẹ̀-èdè wa, lára àwọn ohun tá à ń ṣe láti mú kí iṣẹ́ náà rọrùn ni lílo ìjókòó onígi, ṣáláńgá tàbí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ olómi tá a máa ń lóṣòó lé, kíkun ibi díẹ̀ lára Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣíṣàìkọ́ ilé ẹni tó ń bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣíṣe àwọn ilẹ̀ oní kankéré tó mọ níwọ̀n, lílo àwọn àjà tí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́nwó, àti pé ó lójú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a máa ń fi búlọ́ọ̀kù mọ ọgbà yíká. Àwọn Ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ló ń ṣèpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó mọ níwọ̀n tó sì bójú mu yìí jákèjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

4. Irú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wo la tún ń kọ́, báwo la sì ṣe mú kí ọ̀nà tá a gbà kọ́ ọ rọrùn kó sì mọ níwọ̀n?

4 Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Tó Ṣe É Lò fún Àpèjọ: Ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́dún làwa èèyàn Ọlọ́run máa ń kóra jọ fún àpèjọ àkànṣe, àyíká àti àgbègbè. Láwọn apá ibì kan ní Nàìjíríà, àwọn ará máa ń rìnrìn ọ̀nà jíjìn lọ sáwọn àpèjọ náà. Láwọn apá ibòmíì, àwọn ará kan máa ń sọdá odò kí wọ́n lè lọ sáwọn àpèjọ wọ̀nyí. Káwọn ará wọ̀nyí bàa lè ní àwọn ibi àpèjọ tó bójú mu, a ti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba bíi mélòó kan tó ṣeé lò fún àpèjọ. A kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọ̀nyí lọ́nà tá a tún fi lè lò wọ́n fún àwọn àpèjọ láfikún sáwọn ìpàdé ìjọ. Ara ètò tá a ṣe láti mú kí Gbọ̀ngàn yìí mọ níwọ̀n ni pé, kò ní ògiri lẹ́gbẹ̀ẹ́, pèpéle tó wà níbẹ̀ kò ga, ilẹ̀ ibẹ̀ kò dagun, àwọn àga tó wà níbẹ̀ kò ní ibi téèyàn lè fẹ̀yìn tì, kí àyè lè gba àga tó pọ̀. Nítorí pé àyè ìjókòó tó wà níbẹ̀ kò pọ̀, ńṣe la máa ń pín àwọn àyíká kan tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àwọn àpèjọ wọn.

5. (a) Àwọn ọ̀nà tó mọ níwọ̀n wo la gbà ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Àpèjọ? (b) Báwo la ṣe ń kọ́ àwọn ilé gbígbé tó wà láwọn Gbọ̀ngàn Àpèjọ náà?

5 Àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ: Báwọn àyíká tó pọ̀ tó bá nílò Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ẹ̀ka ọ́fíìsì á rí sí bá a ó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ. Bá a ṣe ń parí àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tá a kọ́ kù láàbọ̀, bẹ́ẹ̀ náà là ń kọ́ tuntun tó mọ níwọ̀n. Àwọn Gbọ̀ngàn Àpèjọ tuntun yìí kì í fẹ̀, kì í ní ògiri lẹ́gbẹ̀ẹ́, ilẹ̀ ibẹ̀ máa ń dagun díẹ̀, ìwọ̀nba ọ́fíìsì àti ilé ìgbọ̀nsẹ̀ olómi tá a máa ń lóṣòó lé ló sì máa ń wà níbẹ̀. Bákan náà, a tún lè kọ́ ilé gbígbé kan tàbí méjì síbẹ̀, àmọ́ èyí jẹ́ láwọn ibi tí kò bá ti rọrùn láti rí ilé gbígbé nítòsí. Àwọn ilé gbígbé wọ̀nyí jẹ́ èyí tó mọ níwọ̀n tá a fi búlọ́ọ̀kù lásán kọ́ tá a sì fi kankéré ṣe àwọn ilẹ̀ rẹ̀. A ò kọ́ àwọn ilé yìí láti lè fi gbogbo àwọn tó bá wá sí àpèjọ wọ̀ sí o, àmọ́ kìkì àwọn tó bá nílò ìrànlọ́wọ́ jù lọ ló wà fún. Láwọn ìgbà míì tí ibùgbé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpèjọ kò bá tó, ẹ̀ka tó ń bójú tó ilé gbígbé ló máa ṣètò fún ibùgbé, bóyá láwọn ilé àdáni, òtẹ́ẹ̀lì, ilé ìwé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣíṣe Nǹkan Lọ́nà Tó Mọ Níwọ̀n Ń Sèso Rere

6. Kí ló ti jẹ́ àbájáde kíkọ́ tá à ń kọ́ àwọn ibi ìjọsìn wa lọ́nà tó mọ níwọ̀n?

6 Kí ló ti jẹ́ àbájáde kíkọ́ tá à ń kọ́ àwọn ibi ìjọsìn wa lọ́nà tó mọ níwọ̀n yìí? Ó ti ṣeé ṣe fún ètò Ọlọ́run láti ṣèrànwọ́ nínú kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn púpọ̀ sí i pẹ̀lú ìwọ̀nba owó àtàwọn ohun èlò tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Èyí sì mú káwọn ará púpọ̀ sí i ní àwọn ibi ìjọsìn tó bójú mu. (2 Kọ́r. 8:10-15) Bákan náà, lílo àwọn ọ̀nà ìkọ́lé àtàwọn ohun èlò tó rọrùn tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀ ń mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ará yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà, èyí ń mú kí iṣẹ́ náà yára kánkán kó sì parí láàárín àkókò kúkúrú. Àwọn ohun ìkọ́lé tó mọ níwọ̀n tá a máa ń lò sára ilé ń mú kí bíbójú tó wọn rọrùn kó má sì náni lówó púpọ̀, èyí sì ń mú kí apá àwọn ìjọ àti àyíká tó ń lò wọ́n ká ṣíṣe àbójútó wọn.—Gál. 6:5; Fílí. 1:10.

7, 8. Ǹjẹ́ Jèhófà ń bù kún ètò tá a ṣe fún kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn wa lọ́nà tó mọ níwọ̀n? Fúnni ní ẹ̀rí tó fi hàn bẹ́ẹ̀.

7 Kò sí àníàní pé Jèhófà ń bù kún ètò tá a ṣe fún kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn wa lọ́nà tó mọ níwọ̀n yìí. Oṣù November 1999 la bẹ̀rẹ̀ ètò ìkọ́lé yìí, nígbà tó fi máa di oṣú March 2008, àpapọ̀ iye Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ti kọ́ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán dín mẹ́jọ [16,992], ní àádọ́fà ó lé mẹ́rin [114] orílẹ̀-èdè. Ẹgbàá ó lé mọ́kànlá [2,011] lára àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọ̀nyí la kọ́ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Láàárín àkókò kan náà, a ti kọ́ àwọn ibi àpèjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] parí ní Nàìjíríà, yálà àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ṣe é lò fún àpèjọ tàbí àwọn Gbọ̀ngàn Àpèjọ. Gbogbo ìwọ̀nyí ló ti mú káwọn èèyàn mọ orúkọ Jèhófà kí wọ́n sì mọ̀ nípa Ìjọba rẹ̀.

8 Nígbà tí wọ́n ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní ìpínlẹ̀ Delta, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará ló ti ṣọ́ọ̀bù wọn tí wọ́n sì yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ náà. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí wọ́n parí iṣẹ́, olùfìfẹ́hàn kan tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti báwọn ṣiṣẹ́ sọ pé: “Ẹ̀yin gan-an lẹ̀ ń ṣe ìsìn tòótọ́. Ó wù mí kí n dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn yín pátápátá.” Ọkùnrin yìí ń tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kò sì pẹ́ tó fi di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, nígbà tí baálẹ̀ abúlé kan gbọ́ pé wọ́n já òkúta tá a fẹ́ fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba síbi tó jìn sí ibi tí wọ́n fẹ́ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà sí, nítorí pé ojú ọ̀nà ibẹ̀ kò dáa, ló bá ṣètò pé kí gbogbo àwọn ará abúlé náà tún ọ̀nà yẹn ṣe fún ọ̀sẹ̀ kan. Wọ́n fi òkúta dí gbogbo àwọn ibi tí kòtò wà. Bákan náà, ó tún gba ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ láyè láti máa lọ sáwọn ìpàdé wa. Baálẹ̀ náà wá sọ pé: “Inú mi dùn pé irú nǹkan báyìí ń ṣẹlẹ̀ lábúlé mi.”

Ṣíṣètìlẹyìn Fáwọn Ibi Ìjọsìn Wa Tó Mọ Níwọ̀n

9. Ọ̀nà mẹ́ta wo la lè gbà ṣètìlẹ́yìn fáwọn ibi ìjọsìn wa?

9 Ó yẹ káwa èèyàn Jèhófà máa fi tọkàntọkàn ṣètìlẹ́yìn fáwọn ètò yìí. A mọyì àwọn ibi ìjọsìn wa tó ń ṣàgbéyọ orúkọ Jèhófà. A ò fẹ́ káwọn ibi ìjọsìn wọ̀nyí tàbùkù sí ìjọsìn tá à ń ṣe. Nígbà náà, kí la lè ṣe? A lè kópa nínú (1) bíbójútó wọn, (2) lílò wọ́n lọ́nà tó dára fún ìdí tá a fi kọ́ wọn, àti (3) fífowó ṣètìlẹ́yìn fún ìlò àti àbójútó wọn. Bíi tàwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì, àwa pẹ̀lú fẹ́ ṣe “bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́” láwọn apá tá a mẹ́nu kàn yìí.—Jẹ́n. 6:22; Ẹ́kís. 7:6.

10. Láwọn apá wo la ti lè kópa nínú bíbójú tó àwọn ibi ìpàdé wa?

10 Àbójútó: Kò sí ilé tí kò nílò àbójútó, ṣíṣe àbójútó sì rèé máa ń béèrè pé ká lo owó àti okun wa. Ó gba pé ká fowó ṣètìlẹ́yìn ká sì yọ̀ǹda ara wa láti lè kúnjú àìní yìí. Àǹfààní ló sì jẹ́ láti kópa nínú apá méjèèjì yìí. Láti lè máa bójú tó àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn alàgbà ìjọ máa ń ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún àbójútó wọn. Lára àwọn iṣẹ́ àbójútó náà ni gbígbá ilẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé, ṣíṣe ìmọ́tótó Gbọ̀ngàn Ìjọba lóṣooṣù, gígé àwọn koríko, gígé àwọn ẹ̀ka igi àti igbó. Láwọn ìgbà míì sì rèé, ó máa gba pé ká tún un kùn tàbí ká ṣe àwọn àtúnṣe pàtàkì kan. A máa ń pe àwọn ìjọ tàbí àyíká lóòrèkóòrè láti wá ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ìmọ́tótó àti àbójútó àwọn Gbọ̀ngàn Àpèjọ. Nígbà míì, a máa ń nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ bíi oníṣẹ́ ẹ̀rọ omi, atúnnáṣe, bíríkìlà, káfíńtà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ láti wá ṣe àwọn iṣẹ́ kan ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibi àpèjọ. Bá a bá ń fi tinútinú yọ̀ǹda ara wa tá a sì ń lo òye iṣẹ́ tá a mọ̀ lọ́nà tó gbéṣẹ́ nígbàkigbà tí wọ́n bá pè wá láti wá ṣèrànwọ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ àbójútó náà.—Sm. 110:3.

11. Báwo la ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fáwọn ibi ìjọsìn wa tá a bá wà láwọn ìpàdé àti àpèjọ?

11 Máa Lò Ó Bó Ṣe Yẹ: A kọ́ àwọn ibi ìpàdé wa ká lè máa jọ́sìn níbẹ̀, ohun tó sì yẹ ká máa lò wọ́n fún náà nìyẹn. Èyí sì gba pé ká máa hùwà lọ́nà tó máa fi ọ̀wọ̀ àti ìmọrírì hàn fáwọn nǹkan tẹ̀mí. (1 Kọ́r. 10:31) Bí àpẹẹrẹ, bá ò bá lo àwọn ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wa bó ṣe yẹ, àwọn nǹkan olówó iyebíye lè bà jẹ́. Tá a bá ń lo omi nílòkulò, ó lè máà jẹ́ káwọn ẹlòmíì rí omi lò, ńṣe la sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi owó tá a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣòfò. Bá a bá ń fi igi tàbí sítóòfù tó ń ṣèéfín dáná láwọn ibi àpèjọ, ó lè mú kí ilé ìdáná máà bójú mu. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni lórí bá a ó ṣe máa lo àwọn nǹkan wọ̀nyí. Gbogbo nǹkan tó wà láwọn ibi ìpàdé wa, tó fi mọ́ àwọn ọ́fíìsì tó wà láwọn Gbọ̀ngàn Àpèjọ ló yẹ ká máa lò fún ìjọsìn Jèhófà. Ní Gbọ̀ngàn Àpèjọ kan, ọmọdé kan ba nǹkan jẹ́ ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀ torí pé kò lò ó bó ṣe yẹ, ó sì ná wa lówó púpọ̀. Nítorí náà, bébà ìnùdí, [tissue paper] àti omi nìkan la gbọ́dọ̀ máa lò, ká má bàa dí ihò ilé ìgbọ̀nsẹ̀ pa. Ní gbogbo Gbọ̀ngàn Àpèjọ àti Gbọ̀ngàn Ìjọba, síso àwọn ohun èlò àdáni bíi fóònù alágbèéká mọ́ ara iná mànàmáná kì í jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀, ó sì máa ń dẹrù pa iná mànàmáná. Jèhófà la ya àwọn ibi ìpàdé wa sí mímọ́ fún, torí náà, ìjọsìn Jèhófà nìkan la gbọ́dọ̀ máa lò wọ́n fún. Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ lo àǹfààní wíwá sáwọn ìpàdé fún ṣíṣe òwò. A gbọ́dọ̀ sapá gidigidi láti jẹ́ kí ìwà wa àti tàwọn ọmọ wa láwọn ibi ìjọsìn wọ̀nyí máa fi hàn pé ìsìn tòótọ́ là ń ṣe.

12. Báwo la ṣe ń rí owó tá à ń ná sórí àbójútó àwọn ibi ìpàdé wa? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé karùn-ún àtèyí tó wà lábẹ́ rẹ̀.)

12 Fífowó Ṣètìlẹ́yìn: Ká lè máa rí owó láti fi bójú tó àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, a máa ń fowó sínú àpótí tá a kọ “Ìnáwó Ìjọ” sí lára ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa. Láti rí owó tá a fi ń bójú tó àwọn ibi àpèjọ wa, a máa ń fowó sínú èyíkéyìí lára àwọn àpótí tó wà láwọn ibi àpèjọ wa tá a bá lọ sí àpéjọ àyíká tàbí àkànṣe. (Wo àpótí tó wà lójú ìwé karùn-ún àtèyí tó wà lábẹ́ rẹ̀ fún àlàyé kíkún lórí owó tá a fi ń ṣètìlẹ́yìn fáwọn ibi ìpàdé wa.) Irú ọwọ́ wo ló yẹ ká máa fi mú ṣíṣe ìtìlẹ́yìn yìí? Ńṣe ló yẹ ká máa wò ó gẹ́gẹ́ bí ara ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn Jèhófà.— Òwe 3:9, 10; 2 Kọ́r. 9:7.

13, 14. Báwo ni gbogbo wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ ṣe lè fi hàn pé à ń ṣètìlẹ́yìn tá a sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ètò tá a ṣe nípa kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn lọ́nà tó mọ níwọ̀n?

13 A ò ní jẹ́ kí ‘ọwọ́ wa rọ jọwọrọ’ tàbí ká “ṣàìnáání ilé Ọlọ́run wa,” nípa fífowó ṣíṣètìlẹyìn déédéé fún àbójútó àwọn ibi ìpàdé wa. A ń tipa bẹ́ẹ̀ fìmọrírì hàn fún ètò yìí, tá a sì ń fẹ́ káwọn ẹlòmíì pẹ̀lú jàǹfààní nínú rẹ̀. (2 Kíró. 15:7; Neh. 10:32, 39b) A máa ń ta àwọn dúkìá tí kò ṣeé lò fún ibi ìpàdé, a sì máa ń lo àwọn owó tá a bá rí níbẹ̀ fún kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn wa. Kódà báwọn ará kan bá fẹ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba ńlá tó jojú ní gbèsè, a fẹ́ nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìlànà tó wà fún èyí tó mọníwọ̀n níbàámu pẹ̀lú ipò àyíká ibi kọ̀ọ̀kan. (2 Kọ́r. 8:14, 15) Táwọn nǹkan kan bá bà jẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ká tètè ṣàtúnṣe wọn kó tó di pé àwọn ìṣòro míì á tún yọjú.

14 Àkókó tó ṣe pàtàkì táwọn èèyàn Ọlọ́run ń fìtara ńláǹlà hàn la wà yìí. “Ní gbígbẹ́kẹ̀lé ìfohùnṣọ̀kan” wa pẹ̀lú àwọn nǹkan tá a ti ń jíròrò bọ̀ nínú àkìbọnú yìí, ó dá wa lójú pé bẹ́ ẹ ṣe ń fínnúfíndọ̀ lo òye iṣẹ́ yín, ara yín àti owó yín, pẹ̀lú bẹ́ẹ̀ ṣe ń fìṣọ́ra lo àwọn ibi ìpàdé wa tó mọ níwọ̀n, síbẹ̀ tó ń buyì kúnni yìí á máa bá a nìṣó láti fi hàn pé tinútinú la fi ń tẹ̀ lé ètò Jèhófà.—Fílém. 21.

[Àpótí tó wà lójú ewé 5]

FÍFOWÓ ṢÈTÌLẸ́YÌN FÀWỌN GBỌ̀NGÀN ÌJỌBA

◼ Fún Gbọ̀ngàn Ìjọba Tá A Fẹ́ Kọ́ Lọ́jọ́ Iwájú: Àwọn ìjọ tó bá ń gbèrò àtikọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lè pinnu láti máa ya owó kan sọ́tọ̀ fún èyí. Wọ́n á máa fowó yìí sínú àpótí tí wọ́n kọ “Ìnáwó Ìjọ” sí lára nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n á máa fowó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lóṣooṣù, kí wọ́n lo fọ́ọ̀mù Contribution Remittance Form (S-20).

◼ Fún Ìlò Gbọ̀ngàn Ìjọba: Gbogbo ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ti kọ́ parí máa ń fowó ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lóṣooṣù fún ìlò Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. A ó máa fowó yìí sínú àpótí tí wọ́n kọ “Ìnáwó Ìjọ” sí lára nínu Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n á máa fàwọn owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lóṣooṣù, kí wọ́n lo fọ́ọ̀mù Contribution Remittance Form (S-20).

◼ Fún Ìṣètò Ìrànlọ́wọ́ fún Gbọ̀ngàn Ìjọba: Gbogbo ìjọ tó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba pinnu láti máa fowó ṣètìlẹ́yìn lóṣooṣù fún ètò yìí ká lè rówó ná tí nǹkan bá bà jẹ́ tàbí fún ìbánigbófò tí ìjàǹbá bá ṣẹlẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. A ó máa fowó yìí sínú àpótí tí wọ́n kọ “ìnáwó Ìjọ” sí lára nínu Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n á máa fàwọn owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lóṣooṣù tàbí lọ́dọọdún, kí wọ́n lo fọ́ọ̀mù Contribution Remittance Form (S-20).

◼ Fún Ìnáwó Àbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba: Ojúṣe Ìjọ kọ̀ọ̀kan ni láti máa fowó ṣètìlẹ́yìn fún àbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba, yálà fún àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tàbí àtúnṣe pàtàkì tó bá yẹ bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́. Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà á pinnu iye tí ìjọ á máa fi ṣètìlẹ́yìn lóṣooṣù fún àbójútó yìí, wọ́n á sì sọ fún ìjọ. A ó máa fi owó yìí sínú àpótí tí wọ́n kọ “Ìnáwó Ìjọ” sí lára nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. A rọ àwọn ìjọ pé kí wọ́n ṣí àkáǹtì fún èyí. Tàbí kẹ̀, ẹ lè fowó yìí pà mọ́ sọ́wọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì, á sì wà lábẹ́ ètò tá a ṣe fún owó tí ìjọ san sílẹ̀.

◼ Fún Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Kárí Ayé: Èyí wà fún fífowó ṣètìlẹ́yìn fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, yálà lórílẹ̀-èdè wa tàbí níbòmíì. A ó máa fowó yìí sínú àpótí tá a kọ “Ọrẹ fun Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Kárí Ayé” sí lára, a ó sì máa fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lóṣooṣù. Gbogbo ìjọ láǹfààní láti máa ṣe ìtìlẹ́yìn yìí, kódà tí wọ́n bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé kan lọ́wọ́lọ́wọ́. Kì í ṣe Ìlò Gbọ̀ngàn Ìjọba yín ni ọrẹ yìí wà fún o, àmọ́ ètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Kárí ayé ló wà fún.

[Àpótí tó wà lójú ewé 6]

FÍFOWÓ ṢÈTÌLẸ́YÌN FÁWỌN IBI ÀPÈJỌ

◼ Fún Ìlò Àwọn Ibi Àpèjọ: Gbogbo ìjọ pinnu láti máa fowó ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lóṣooṣù fún ìlò àwọn ibi àpèjọ, yálà Gbọ̀ngàn Àpèjọ tàbí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ṣeé lò fún àpèjọ. A ó máa fi owó yìí sínú àpótí tí wọ́n kọ “Ìnáwó Ìjọ” sí lára nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n máa ń fi owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lóṣooṣù, kí wọ́n lo fọ́ọ̀mù Contribution Remittance Form (S-20). Gbogbo owó tá a bá rí nínú àwọn àpótí láwọn àpéjọ àgbègbè la ó lò fún iṣẹ́ kárí ayé, tó fi mọ́ kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti Gbọ̀ngàn Ìjọba.

◼ Fún Owó Tá À Ń Ná Sórí Àbójútó Àwọn Ibi Àpèjọ: Ojúṣe àwọn àyíká tó ń lo ibi àpèjọ ni láti pèsè owó tí wọ́n á máa fi bójú tó o. Èyí á sì sinmi lórí ohun tí wọ́n bá fẹ́ gbé ṣe lọ́dún kan. Akéde kọ̀ọ̀kan máa ń fowó sínú àwọn àpótí tó wà làwọn ibi àpèjọ yìí láti ṣètìlẹ́yìn fún àbójútó náà tí wọ́n bá lọ sáwọn àpéjọ àyíká àti àkànṣe. Nígbà tí àìní bá wà, bóyá táwọn àyíká tó ń lo ibi àpèjọ kan kò bá ní owó tó pọ̀ tó lọ́wọ́ láti bójú tó ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, alábòójútó àyíká á sọ fáwọn ìjọ pé kí wọ́n pinnu iye tí wọ́n máa fi ṣètìlẹ́yìn fáwọn ìnáwó náà.—Wo ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 130.

[Àwòrán tó wà lójú ewé 3]

Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ṣeé lò fún àpèjọ, Kaduna

[Àwòrán tó wà lójú ewé 4]

Gbọ̀ngàn Ìjọba, Mayowa

[Àwòrán tó wà lójú ewé 5]

Gbọ̀ngàn Àpéjọ, Benin City

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́