Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 26
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 26
Orin 32
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 17-20
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 17:1-17
No. 2: Kí Ni Ọkàn? (td-YR 40A)
No. 3: Ọlọ́run Ní Orúkọ Kan (lr orí 4)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 197
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
10 min: Múra Sílẹ̀ láti Lo Ilé Ìṣọ́ February 1 àti Jí! January–March.Lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ ṣókí lórí àwọn ìwé ìròyìn yìí, ní káwọn ará sọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀. Ní kí wọ́n mẹ́nu ba àwọn kókó kan látinú àwọn àpilẹ̀kọ ti wọ́n ní lọ́kàn láti lò lóde ẹ̀rí. Ìbéèrè wo ni wọ́n lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wọ́n máa fẹ́ kà látinú àpilẹ̀kọ náà? Níparí ọ̀rọ̀ rẹ, lo àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a dábàá lójú ìwé 4 tàbí àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tí àwùjọ dábàá láti ṣàṣefihàn ọ̀nà tá a lè gbà fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù February. Ní ṣókí, sọ àwọn kókó ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé náà, kó o sì ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì.
10 min: ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.’a Sọ àwọn nǹkan pàtàkì-pàtàkì tó wà nínú ìwé náà. Gba àwọn ará níyànjú láti máa wá sípàdé déédéé, kí wọ́n sì máa lóhùn sí i dáadáa.
Orin 180
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.