ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/09 ojú ìwé 3
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 4/09 ojú ìwé 3

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 27, 2009. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ March 2 sí April 27, 2009, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.

1. Kí ni Jósẹ́fù ṣe láti kojú àwọn àdánwò tó ń dojú kọ lójoojúmọ́? (Jẹ́n. 39:7-12) [lv-YR ojú ìwé 105 ìpínrọ̀ 18 sí ojú ìwé 106 ìpínrọ̀ 20]

2. Kí ni Bíbélì sọ nípa ayẹyẹ ọjọ́ ìbí? (Jẹ́n. 40:20-22) [lv-YR ojú ìwé 150 ìpínrọ̀ 9 sí ojú ìwé 151 ìpínrọ̀ 11]

3. Báwo ni Jósẹ́fù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ tó ta yọ tá a lè fara wé tọ́ràn bá kan pé ká dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá? (Jẹ́n. 45:4, 5) [w99 1/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2 àti 3]

4. Jósẹ́fù sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí ẹ kó egungun mi gòkè kúrò níhìn-ín.” Báwo lọ̀rọ̀ tó sọ yìí ṣe nípa lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (Jẹ́n. 50:25) [w07 6/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 10]

5. Kí ló lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ nígbà tá a bá ń bójú tó àwọn ojúṣe kan tó dà bíi pé ó ṣòro? (Ẹ́kís. 4:10, 13) [w04 3/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 5]

6. Kí làwọn èèyàn wá mọ̀ látinú ohun tí Jèhófà ṣe fún Fáráò, báwo sì làwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ wọ̀nyẹn ṣe kàn wá? (Ẹ́kís. 9:13-16) [w05 5/15 ojú ìwé 21 àti 22 ìpínrọ̀ 8]

7. Kí lohun tó wà nínú ìwé Ẹ́kísódù 14:30, 31 túmọ̀ sí fún wa lónìí? [w04 3/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 6]

8. Bó ṣe wà nínú ìwé Ẹ́kísódù 16:1-3, kí ló burú nínú kéèyàn máa ráhùn? [w93 3/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 2]

9. Níbàámu pẹ̀lú Májẹ̀mú Òfin tó wà nínú ìwé Ẹ́kísódù 19:5, 6, dé ìwọ̀n àyè wo la fi lè sọ pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì jẹ́ “ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́”? [w95 7/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 8]

10. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé òfin kẹwàá tó dá lórí ojúkòkòrò ju gbogbo òfin táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ lọ? (Ẹ́kís. 20:17) [w06 6/15 ojú ìwé 23 àti 24 ìpínrọ̀ 16]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́