Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 20
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 20
Orin 8
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 15-18
No. 1: Ẹ́kísódù 15:1-19
No. 2: Àwọn Ọ̀nà Wo Lèèyàn Lè Gbà Yẹra fún Ẹ̀sìn Èké?
No. 3: Ẹ̀kọ́ Nípa Jíjẹ́ Onínúure (lr orí 15)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 49
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Bíbélì ní ìmísí Ọlọ́run. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Apá 4 ìpínrọ̀ 1 sí 10.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Ilé Ìṣọ́ May 1 àti Jí! April–June. Ní káwọn ará sọ àpilẹ̀kọ tí wọ́n rò pé ó máa fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín àti ìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀. Ṣàṣefihàn bá a ṣe lè lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà. Kí ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà dá lórí béèyàn ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà ìpadàbẹ̀wò.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti August, 2007 ojú ìwé 3.
10 min: “Kọ́ Àwọn Tí Ò Fi Bẹ́ẹ̀ Mọ̀wé Kà Lẹ́kọ̀ọ́.” Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, ṣàṣefihàn bí aṣáájú ọ̀nà kan ṣe lo àwòrán tó wà nínú ìwé tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́.
Orin 170