Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 25
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 25
Orin 74
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 34-37
No. 1: Ẹ́kísódù 37:1-24
No. 2: Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Jà? (lr orí 19)
No. 3: Kí Ni Ìgbọ̀jẹ̀gẹ́, Kí sì Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Gbọ̀jẹ̀gẹ́?
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 193
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Ilé Ìṣọ́ June 1 àti Jí! April–June. Lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ ṣókí lórí àwọn ìwé ìròyìn yìí, ní káwọn ará sọ àpilẹ̀kọ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì sọ ìdí. Ní kí wọ́n sọ ìbéèrè tí wọ́n lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n máa fẹ́ kà. Ṣàṣefihàn bá a ṣe lè lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.
10 min: Jíjẹ́rìí Jésù. Àsọyé tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, Jíjẹ́rìí Jésù, ojú ìwé 275, ìpínrọ̀ mẹ́rin àkọ́kọ́.
10 min: “Máa Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa Lọ́nà Tó Dáa.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ ń béèrè fún àti iye tẹ́ ẹ̀ ń ròyìn pé ẹ fi sóde.
Orin 123