ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/09 ojú ìwé 4
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 5/09 ojú ìwé 4

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé tá a máa lò lóṣù May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la máa lò. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣèpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kì í ṣe déédéé nínú ìjọ, ẹ sapá láti fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn. June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé olójú ìwé 192 èyíkéyìí tá a tẹ̀ sórí bébà tó pọ́n ràkọ̀ràkọ̀ tàbí ìwé èyíkéyìí tá a tẹ̀ ṣáájú ọdún 1992. July àti August: Àwọn ará lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé olójú ìwé 32 tó bá wà lọ́wọ́: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye—Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, àti “Sawo o! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”.

◼ Kí ẹni tó bá fẹ́ fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé nípasẹ̀ ìwé sọ̀wédowó ní àpéjọ àgbègbè àtèyí tá a bá fẹ́ fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ “Watch Tower” sórí ìwé sọ̀wédowó náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n máa sanwó fún. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kọ́ Watch àti Tower lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ni o.

◼ Kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà jíròrò lẹ́tà July 6, 2006, èyí tó sọ nípa bí wọ́n ṣe lè múra sílẹ̀ de àjálù, kí wọ́n sì rí i pé àdírẹ́sì ibi tí akéde kọ̀ọ̀kan ń gbé wà lọ́wọ́ àwọn. Láwọn àdúgbò tí àjálù ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀, kẹ́ ẹ rí i pé ẹ béèrè ọ̀nà míì tẹ́ ẹ lè gbà kàn sí wọn bí ọ̀ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀. Bákan náà, yàtọ̀ sí ọ̀ràn pàjáwìrì, ó tún máa ń dáa táwọn akéde bá lè máa fi tó alábòójútó Àwùjọ wọn tàbí alàgbà míì létí tí wọ́n bá fẹ́ rìnrìn àjò fún àkókò gígùn, bóyá lásìkò tí wọ́n bá gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, tí wọ́n bá wà ní ilé ìwòsàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́