Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 1
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 1
Orin 26
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 38-40
No. 1: Ẹ́kísódù 40:1-19
No. 2: Ǹjẹ́ O Máa Ń Fẹ́ Jẹ́ Ẹni Àkọ́kọ́ Nígbà Gbogbo? (lr orí 20)
No. 3: Ẹ̀mí Mímọ́ Kì Í Ṣe Ẹnì Kan (td-YR 36E)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 129
5 min: Àwọn ìfilọ̀. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù May sílẹ̀.
10 min: Ran Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́ Láti Tẹ̀ Síwájú. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 187 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 188 ìpínrọ̀ 3. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu aṣáájú-ọ̀nà tàbí akéde kan tó ti ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú.
10 min: Lo Ìwé 2009 Yearbook Lọ́nà Tó Dáa. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Jíròrò “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí,” tó jẹ́ àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù March 2009. Ṣètò pé kí ẹnì kan tàbí méjì tó o ti sọ fún tẹ́lẹ̀ sọ ìrírí tó fún wọn níṣìírí látinú ìwé ọdọọdún náà. Ní káwọn ará sọ apá tó fani mọ́ra nínú ìròyìn iṣẹ́ ìsìn kárí ayé, ìyẹn worldwide report. Mú ọ̀rọ̀ rẹ wá sí ìparí nípa gbígba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n ka ìwé yìí láti páálí dé páálí.
10 min: Àṣeyọrí Wo La Ṣe? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Gbóríyìn fún àwọn ará fún bí wọ́n ṣe fi kún iṣẹ́ ìsìn wọn lákòókò Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì sọ̀rọ̀ lórí ohun pàtó kan tẹ́ ẹ gbé ṣe. Ní káwọn ará sọ ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń pín ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí nígbà tí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
Orin 53