Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 27
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 27
Orin 77
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR Àfikún ojú ìwé 215 sí 218
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Númérì 1-3
No. 1: Númérì 3:1-20
No. 2: Ìdí Tó Fi Gba Ìkóra-Ẹni-Níjàánu Kéèyàn Tó Lè Jẹ́ Oníwà Tútù
No. 3: Ta Ni Ọlọ́run Rẹ? (lr orí 27)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 131
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Máa Lo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Múná Dóko. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 236 sí ojú ìwé 237, ìpínrọ̀ 2. Ní ṣókí, ṣàṣefihàn kókó kan tàbí méjì látinú àpilẹ̀kọ náà.
10 min: Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn òbí méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Báwo ni wọ́n ṣe ń kojú àwọn ohun tí ì bá mú kó ṣòro fún wọn láti bójú tó iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé? Kí ni wọ́n ti ṣe láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù? Báwo ni wọ́n ṣe ń lo Ìjọsìn Ìdílé láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa lọ sóde ẹ̀rí?
10 min: “Máa Yin Jèhófà Lójoojúmọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 154