Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé tá a máa lò ní October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la máa lò. Ẹ fún ẹni tó bá fìfẹ́ hàn ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? Bó bá ti ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, kẹ́ ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé ògbólógbòó èyíkéyìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ìwé míì tá a tún lè lò gẹ́gẹ́ bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Báwọn ọmọdé bá wà nínú ilé náà, kẹ́ ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. January: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé ògbólógbòó èyíkéyìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ìwé míì tá a tún lè lò gẹ́gẹ́ bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà.
◼ A kò ní máa fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti ọdọọdún sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la ó máa fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ránṣẹ́ sí ìjọ. Kí wọ́n lẹ ẹ̀dà kan mọ́ pátákó ìsọfúnni ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ tọ́jú ẹ̀dà kan kó lè máa fi yan iṣẹ́ fáwọn ará. Àwọn akéde á ṣì máa gba ẹ̀dà Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lóṣooṣù, ibẹ̀ ni wọ́n á sì ti máa rí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ March 1, ọdún 2010, ìwé “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn” la ó máa lò ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Kí àwọn ìjọ tó bá nílò ìwé yìí béèrè fún un nígbà tí wọ́n bá tún fẹ́ béèrè ìwé.