Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 2
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 2
Orin 115
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 14-18
No. 1: Diutarónómì 15:1-15
No. 2: Kí Ni Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Túmọ̀ Sí?
No. 3: Ọlọ́run Rántí Ọmọ Rẹ̀ (lr orí 39)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 1
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ní káwọn akéde kan tó o ti sọ fún tẹ́lẹ̀ sọ ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́jọ́ tí ìjọ yà sọ́tọ̀ fún ìgbòkègbodò àkànṣe yìí. Sọ ọjọ́ tó kàn tí ìjọ yín máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lákànṣe, kó o sì ṣàṣefihàn kan tàbí méjì ní ṣókí tó fi bá a ṣe lè ṣe é hàn.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Fi Lẹ́tà Wàásù. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 71 sí 73.
Orin 9