Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 26, 2009.
1. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ló sọ pé kí Báláámù báwọn èèyàn Bálákì lọ, kí nìdí tí ìbínú Jèhófà fi ru sí Báláámù nítorí pé ó lọ pẹ̀lú wọn? (Núm. 22:20-22) [w04 8/1 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3]
2. Báwo ni bí Fíníhásì ò ‘ṣe fàyè gba bíbá Jèhófà díje’ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ lori ìyàsímímọ́ wa sí Ọlọ́run? (Núm. 25:11) [w95 3/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 13]
3. Kí nìdí tí Jèhófà fi yan Jóṣúà láti gbapò Mósè? (Núm. 27:15-19) [w02 12/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 1]
4. Bawo lohun tó wà ní Númérì 31:27 ṣe lè fáwọn Kristẹni níṣìírí lónìí? [w05 3/15 ojú ìwé 24]
5. Àwọn ọ̀nà wo làwọn tó ń gbé ní Ísírẹ́lì gbà jàǹfààní látinú ètò fún níní àwọn ìlú ààbò? (Núm. 35:11, 12) [w95 11/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 17]
6. Kí nìdí tí jíjẹ́ olóye fi jẹ́ ànímọ́ pàtàkì tó yẹ kí Kristẹni ní, àǹfààní wo ló sì wà níbẹ̀? (Diu. 1:13) [w03 1/15 30; w00 10/1 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
7. Àwọn ọ̀nà wo ni Òfin Mósè gbà fi òdodo Ọlọ́run hàn? (Diu. 4:8) [w02 6/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 8 sí ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 10]
8. Níbàámu pẹ̀lú Diutarónómì 6:16-18, ṣàlàyé ọ̀nà tó tọ́ àti ọ̀nà tí kò tọ́ láti gbà dán Jèhófà wò. [w04 9/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1]
9. Báwo ni Jèhófà ṣe bójú tó àìní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ àwọn àsọjáde rẹ̀, báwo sì làwọn àsọjáde yẹn ṣe lè pa àwa náà mọ́ láàyè lónìí? (Diu. 8:3) [w99 8/15 ojú ìwé 25-26]
10. Báwo lohun tó wà nínú Diutarónómì 12:16, 24 ṣe lè nípa lórí ojú tá a fi ń wo lílo ẹ̀jẹ̀ tiwa fúnra wa fún ìtọ́jú ìṣègùn? [w00 10/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 7]