Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní November: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé ògbólógbòó èyíkéyìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ìwé míì tá a tún lè lò gẹ́gẹ́ bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí àwọn ọmọdé bá wà nínú ilé náà, kẹ́ ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. January: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé ògbólógbòó èyíkéyìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ìwé míì tá a tún lè lò gẹ́gẹ́ bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tàbí Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà ni kẹ́ ẹ lò.
◼ Àwọn ìjọ kan wà láwọn apá ibì kan ní gúúsù àti àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tá a ti nílò àwọn alàgbà tó dáńgájíá táá máa múpò iwájú nínú ìjọ. (Ìṣe 16:9, 10) A rọ àwọn alàgbà tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ tàbí àwọn míì láti wò ó bóyá ipò wọn á yọ̀ọ̀da fún wọn láti lọ ṣèrànwọ́ ní ọ̀kan lára àwọn ìjọ yìí. Kí ẹni tó bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 111 sí 112, kó sì kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Nàìjíríà tó bá ń fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i.—Mál. 3:10; Lúùkù 14:28.