Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 26, 2010. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ March 1 sí April 26, 2010, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.
1. Kí ni Náómì ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Jèhófà ni ó tẹ́ mi lógo, Olódùmarè ni ó sì mú ìyọnu àjálù bá mi”? (Rúùtù 1:21) [w05 3/1 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 2]
2. Àwọn ànímọ́ wo ló mú kí Rúùtù jẹ́ “obìnrin títayọ lọ́lá”? (Rúùtù 3:11) [w05 3/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 7]
3. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Ẹlikénà sọ pé, “èmi kò ha sàn fún ọ ju ọmọkùnrin mẹ́wàá lọ” ṣe fún ìyàwó rẹ̀ lókun? (1 Sám. 1:8) [w90 3/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 5 sí 6]
4. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí Ísírẹ́lì béèrè fún ọba? (1 Sám. 8:5) [w05 9/15 ojú ìwé 20, ìpínrọ̀ 17]
5. Nígbà tí Sámúẹ́lì ti “darúgbó, [tó] sì ti hewú,” báwo ló ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere ní ti gbígbàdúrà fáwọn ẹlòmíì, kí lèyí sì fi hàn? (1 Sam. 12:2, 23) [w07 6/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 14 sí 15]
6. Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù fi fi inú rere àrà ọ̀tọ̀ hàn sí àwọn Kénì? (1 Sám. 15:6) [w05 3/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 1]
7. Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù fi bi Dáfídì pé, “Ọmọkùnrin ta ni ọ́, ọmọdékùnrin?” (1 Sám. 17:58) [w07 8/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3 àti 5]
8. Kí la rí kọ́ látinú bí Dáfídì ṣe yanjú ìṣòro ńlá tó ṣẹlẹ̀ ní Gátì? (1 Sám. 21:12, 13) [w05 3/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 4]
9. Báwo ni Jónátánì ṣe fi ìfẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ hàn nígbà tó pọn dandan pé kó ti Dáfídì ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn kó sì fún un níṣìírí? (1 Sám. 23:17) [lv ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 10 àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé ojú ìwé 30]
10. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sọ́ọ̀lù lọ pàdé abẹ́mìílò tó wà nílùú Ẹ́ń-dórì? (1 Sám. 28:8-19) [w05 3/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 8]