Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 26
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 26
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 3 ìpínrọ̀ 20 sí 24 àti àpótí tó wà lójú ìwé 34
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 26-31
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àṣefihàn bí aṣáájú-ọ̀nà kan ṣe máa lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́. Ní kí àwọn ará sọ àpilẹ̀kọ tí wọ́n fẹ́ lò. Kí wọ́n sì sọ ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fẹ́ lò.
20 min: “Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2010 ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Akọ̀wé ìjọ ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Kẹ́ ẹ tó jíròrò àpilẹ̀kọ yìí, kọ́kọ́ ka lẹ́tà March 1, 2010, tá a fi yan ìjọ yín sí àpéjọ àgbègbè.