Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 26
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 26
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 15-17
No. 1: 1 Àwọn Ọba 15:1-15
No. 2: Ṣé Sísọ̀rọ̀ Ní Ahọ́n Àjèjì Jẹ́ Ẹ̀rí Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run? (td 32E)
No. 3: Ìdí Tí Ogun Amágẹ́dọ́nì Fi Gbọ́dọ̀ Jà
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I—Apá Kẹta. Àsọyé tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 114, ìpínrọ̀ 2, sí ojú ìwé 115, ìpínrọ̀ 3. Fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìjọ, tí wọ́n sì ti lọ sí yálà Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tàbí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ní kí wọ́n sọ àwọn àǹfààní tí ilé ẹ̀kọ́ náà ti ṣe fún wọn. Bí irú àwọn akéde bẹ́ẹ̀ kò bá sí ní ìjọ yín, sọ àwọn ìrírí tí ètò Ọlọ́run ti tẹ̀ jáde.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Lóṣù August. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà. Lẹ́yìn náà, yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta, kó o sì ní kí àwùjọ sọ àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan.
10 min: “A Fi Ọgbọ́n Hàn Ní Olódodo Nípasẹ̀ Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.