Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 1
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 1
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 12 ìpínrọ̀ 15 sí 21 àti àpótí tó wà lójú ìwé 127
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 16-20
No. 1: 1 Kíróníkà 17:1-10
No. 2: Ẹ̀rí Pé Ọlọ́run Wà Lóòótọ́ (td 34B)
No. 3: Àwọn Ohun Tí Ìwé Mímọ́ Ní Káwọn Kristẹni Tòótọ́ Sá Fún
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: À Ń Fara Da Onírúurú Àdánwò. Àsọyé tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 176, ìpínrọ̀ 2, sí ojú ìwé 178, ìpínrọ̀ 2. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan nípa ohun tó ràn án lọ́wọ́ kó lè máa bá a nìṣó láti fìtara kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ láìka ìṣòro àìlera tó ń bá a fínra sí.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Ní Oṣù November. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì sọ̀rọ̀ nípa ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà. Yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta, kó o sì ní kí àwùjọ sọ ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà.