Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 29
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 29
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 6-9
No. 1: 2 Kíróníkà 6:12-21
No. 2: Jésù Kristi Jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run àti Ọba Tí A Yàn (td 35A)
No. 3: Bá A Ṣe Lè “Máa Fi Ire Ṣẹ́gun Ibi” (Róòmù 12:21)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: “Àṣàrò àti Àdúrà Ṣe Pàtàkì fún Àwọn Òjíṣẹ́ Onítara.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní kí àwọn ará sọ ìgbà tí wọ́n máa ń ṣàṣàrò.
10 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù December. Ìjíròrò. Sọ ohun tó wà nínú àwọn ìwé náà, kó o sì ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Lóṣù December. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà. Yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta, kó o wá ní kí àwọn ará sọ ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè lò tí wọ́n bá fẹ́ fi ìwé náà lọni. Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà.