Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 18
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 18
Orin 17 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 2 ìpínrọ̀ 16 sí 23 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóòbù 28-32 (10 min.)
No. 1: Jóòbù 30:1-23 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìrìbọmi Jẹ́ Ohun Tí À Ń Béèrè Lọ́wọ́ Kristẹni—td 17A (5 min.)
No. 3: Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ronú Ká A Tó Sọ̀rọ̀—Òwe 16:23 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀. Sọ fún àwọn ará pé kí wọ́n múra sílẹ̀ fún apá tá a máa jíròrò ní ìpàdé iṣẹ́ ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, ìyẹn “Ǹjẹ́ Ò Ń Jàǹfààní Nínú Ìwé Ìròyìn Jí!?”
10 min: Nígbà Táwọn Èèyàn Bá Ní Ká Ṣàlàyé Ọ̀rọ̀. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjoba Ọlọ́run ojú ìwé 177, ìpínrọ̀ 3 sí ìparí ojú ìwé 178. Ṣe àṣefihàn ṣókí kan níbi tí òṣìṣẹ́ kan ti ń bi akéde kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ní ìbéèrè nípa àwọn ohun tá a gbà gbọ́. Akéde náà yíjú sẹ́gbẹ̀ẹ́, ó ń dá nìkan sọ̀rọ̀, ó sáré fọkàn ro bó ṣe máa dáhùn ìbéèrè náà, lẹ́yìn náà, ó wá dáhùn.
10 min: Àpótí Ìbéèrè. Ìjíròrò. Alàgbà ni kó bójú tó apá yìí.
10 min: Àwọn Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Wàásù Ìhìn Rere—Láti Ilé dé Ilé. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa ojú ìwé 92, ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 95, ìpínrọ̀ 2. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n máa ń wàásù láti ilé dé ilé bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní àwọn ìṣòro kan, irú bí àìlera tàbí ìtìjú. Àwọn àǹfààní wo ni wọ́n ti jẹ?
Orin 26 àti Àdúrà