Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 16
Orin 96 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 4 ìpínrọ̀ 1 sí 4, àti àpótí tó wà lójú ìwé 30 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 11-18 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 17:1-15 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Fi Hàn Pé Jèhófà Nìkan Là Ń Jọ́sìn—Róòmù 6:16, 17 (5 min.)
No. 3: Bíbélì Jẹ́ Amọ̀nà Wíwúlò fún Ọjọ́ Wa—td 8B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Lo Ìbéèrè Láti Kọ́ni Lọ́nà tó Múná Dóko—Apá 1. Ìjíròrò tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 236 sí ojú ìwé 237, ìpínrọ̀ 2. Ní ṣókí ṣe àṣefihàn kókó kan tàbí méjì látinú àpilẹ̀kọ náà.
10 min: Àwọn Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Wàásù Ìhìn Rere—Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa ojú ìwé 96, ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 97, ìpínrọ̀ 2. Ṣe àṣefihàn ṣókí kan níbi tí alàgbà kan tí ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tó gba ìwé tá à ń lò lóde ẹ̀rí lóṣù yìí.
10 min: “Ṣé O Lè Máa Kópa Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Láwọn Ọjọ́ Sunday?” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 115 àti Àdúrà