Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 28
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 28
Orin 26 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 13 ìpínrọ̀ 8 sí 16, àti àpótí tó wà lójú ìwé 105 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Orin Sólómọ́nì 1-8 (10 min.)
No. 1: Orin Sólómọ́nì 1:1-17 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Hẹ́ẹ̀lì Kì Í Ṣe Ibi Ìdánilóró—td 16A (5 min.)
No. 3: Báwo La Ṣe Lè Mú Káwọn Èèyàn Máa Bọ̀wọ̀ fún Wa? (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Lo àbá nípa bá a ṣe lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 8, láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù December. Fún àwọn ará ní ìṣírí láti jáde òde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn. Bákan náà, sọ ìwé tá a máa lò lóde ẹ̀rí lóṣù December kó o sì sọ díẹ̀ lára ohun tó wà nínú rẹ̀.
25 min: “Ǹjẹ́ O Lè ‘Ré Kọjá Lọ Sí Makedóníà’?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àkéde kan tó lọ sí orílẹ̀-èdè míì láti mú kí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run gbòòrò sí i, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá wà.
Orin 95 àti Àdúrà