Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Ní oṣù September ọdún 2011, àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ ẹgbàá méjìléláàádọ́jọ àti ọ̀tàlénírínwó dín mẹ́rin [304,456] ló ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn. Àpapọ̀ iye wákàtí tí wọ́n lò lóde ẹ̀rí jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rin, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́ta àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mọ́kàndínláàádọ́ta [4,957,649]. Ká sòótọ́, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ní ìtara fún iṣẹ́ rere, Jèhófà la sì fi èyí jọ!—Jòhánù 5:17.