Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 16
Orin 85 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 19 ìpínrọ̀ 6 sí 11 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jeremáyà 25-28 (10 min.)
No. 1: Jeremáyà 27:1-11 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ohun Tí “Òpin Ayé” Túmọ̀ Sí —td 39A (5 min.)
No. 3: Ohun Tí Ìwé Mímọ́ Sọ Nípa Bíbu Ọlá fún Àwọn Àgbàlagbà (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Kọ́ Bí A Ṣe Ń Jẹ́ Olùkọ́ Tó Múná Dóko—Apá 3. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 59 sí 61.
20 min: “Ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run Ń Lé Òkùnkùn Dà Nù!” Ìbéèrè àti ìdáhùn tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ March 1, 2002, ojú ìwé 9 sí 12, ìpínrọ̀ 7 sí 15. Ní ṣókí, lo àlàyé tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí láti nasẹ̀ ìjíròrò náà. Lẹ́yìn náà, kó o wá darí ìjíròrò náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn, kó o lo àwọn ìbéèrè tó wà fún ìpínrọ̀ 7 sí 15 nínú ìwé ìròyìn náà. Lo ìpínrọ̀ kejì nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí láti parí ìjíròrò náà. Fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n wo fídíò “Jehovah’s Witnesses—Faith in Action, Part 1: Out of Darkness” kí wọ́n lè túbọ̀ lóye kókó tá a jíròrò yìí.
Orin 116 àti Àdúrà