ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/12 ojú ìwé 4
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 1

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 1
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 1
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 9/12 ojú ìwé 4

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 1

Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 1

Orin 103 àti Àdúrà

□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:

bt orí 27 ìpínrọ̀ 10 sí 18 (30 min.)

□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:

Bíbélì kíkà: Dáníẹ́lì 4-6 (10 min.)

No. 1: Dáníẹ́lì 4:18-28 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

No. 2: Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Lọ́wọ́ sí Ìbẹ́mìílò (5 min.)

No. 3: Ọlọ́run Kò Kádàrá Ohunkóhun Mọ́ Èèyàn—td 7A (5 min.)

□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:

Orin 80

5 min: Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé Àkọ́kọ́. Lo àbá tó wà lójú ìwé yìí láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù October. Gba gbogbo àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà.

15 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí Lọ́dún Tó Kọjá? Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ bí ìjọ ṣe ṣe sí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, tẹnu mọ́ ibi tí wọ́n ti ṣe dáadáa, kó o sì gbóríyìn fún àwọn ará. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ní àwọn ìrírí tó wúni lórí. Sọ kókó kan tàbí méjì nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, èyí tí ìjọ ní láti ṣiṣẹ́ lé lórí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó ń bọ̀, kó o sì jíròrò àwọn àbá mélòó kan tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ ṣe dáadáa.

10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù October. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan sọ ìdí táwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé ìròyìn wa ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ October, ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! October–December 2012, tí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ míì nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwé ìròyìn náà lọni.

Orin 85 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́