Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 19
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 19
Orin 81 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr ori 1 ìpínrọ̀ 15 sí 21 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ọbadáyà 1–Jónà 4 (10 min.)
No. 1: Jónà 2:1-10 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Bí Ìjọsìn Tòótọ́ Ṣe Ń Mú Kí Àwọn Èèyàn Tó Wá Láti Ibi Tó Yàtọ̀ Síra Wà Ní Ìṣọ̀kan—Sm. 133:1 (5 min.)
No. 3: Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ń Rí “Ohun Rere Nínú Gbogbo Ẹ̀sìn?”—td 34E (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Tó Ń Sìn Níbi Tí Wọ́n Ti Nílò Oníwàásù Púpọ̀ Sí I. Ìjíròrò tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ April 15, 2009, ojú ìwé 20 sí 23. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
15 min: “Túbọ̀ Sa Gbogbo Ipá Rẹ—Tó O Bá Ń Rò Pé O Kò Tóótun.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tó máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò kàwé púpọ̀ tàbí tó máa ń tijú.
Orin 26 àti Àdúrà