Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 15
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 15
Orin 6 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 8 ìpínrọ̀ 1 sí 7 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Lúùkù 13-17 (10 min.)
No. 1: Lúùkù 16:16-31 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Bá A Tiẹ̀ Jẹ́ Aláìpé, A Ṣeyebíye Lójú Ọlọ́run—Sm. 103:8, 9, 14; Gál. 6:9 (5 min.)
No. 3: Ọmọ Rẹlẹ̀ sí Baba—td 36B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àpótí Ìbéèrè. Ìjíròrò.
10 min: Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I—Apá Kejì. Àsọyé tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 112, ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 114, ìpínrọ̀ 1. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu aṣáájú-ọ̀nà kan tàbí méjì, ní kí wọ́n sọ àwọn àyípadà tí wọ́n ti ṣe kí wọ́n lè ráyè ṣe aṣáájú-ọ̀nà.
10 min: Ǹjẹ́ O Máa Ń Wàásù Níbi Iṣẹ́ Rẹ? Ìjíròrò tó dá lórí àwọn ìbéèrè yìí: (1) Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́? (2) Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀? (3) Àwọn àǹfààní wo lo máa ń ní láti wàásù níbi iṣẹ́? (4) Tó bá ṣeé ṣe, kí nìdí tó fi dáa pé kó o fi Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde míì síbi iṣẹ́ rẹ? (5) Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o lo àkókò tó pọ̀ jù tó o bá ń sọ̀rọ̀ Bíbélì fún àwọn èèyàn lẹ́nu iṣẹ́ rẹ? (6) Ìrírí wo lo ti ní tó dá lórí bó o ṣe wàásù níbi iṣẹ́?
Orin 45 àti Àdúrà