Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 20
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 20
Orin 70 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 9 ìpínrọ̀ 14 sí 19 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jòhánù 8-11 (10 min.)
No. 1: Jòhánù 8:12-30 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo La Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Wa Lọ́wọ́ Àwọn Olùkọ́ Èké?—Róòmù 16:17; 2 Jòh. 9-11 (5 min.)
No. 3: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Burúkú?—td 31B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I—Apá Kẹta. Ìjíròrò tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 116, ìpínrọ̀ 1 sí 4. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Ní kí wọ́n sọ ohun tí wọ́n gbádùn nínú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn náà.
10 min: Jèhófà Ń Tì Wá Lẹ́yìn Ká Lè Ṣe Iṣẹ́ Wa. (Ẹ́kís. 4:10-12; Fílí. 4:13) Ìjíròrò tó dá lórí Ìwé Ọdọọdún 2013, ojú ìwé 102, ìpínrọ̀ 1 àti ojú ìwé 112, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 113, ìpínrọ̀ 1. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: “Àwọn Wo Ló Máa Fẹ́ Ka Àpilẹ̀kọ Yìí?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní kí àwọn ará sọ àwọn oníṣòwò àtàwọn ọ́fíìsì ìjọba tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín tí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn kókó ọ̀rọ̀ kan pàtó nínú àwọn ìwé ìròyìn wa.
Orin 92 àti Àdúrà