ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/13 ojú ìwé 3
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 6/13 ojú ìwé 3

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 24, 2013. A fi déètì tá a máa jíròrò kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan síwájú àwọn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ lè ṣèwádìí wọn nígbà tẹ́ ẹ bá ń múra sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

1. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ ohun tó wà nínú Jòhánù 3:14, 15 pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ náà ni a óò gbé Ọmọ ènìyàn sókè”? [May 6, gt orí 17 ìpínrọ̀ 5]

2. Ìgbà wo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi máa gba ìyè nínú ara wọn, tàbí tí wọ́n á ní ìwàláàyè tó kún rẹ́rẹ́? (Jòh. 6:53) [May 13, w03 9/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3]

3. Ṣàpèjúwe bí Jésù ṣe fi ànímọ́ Baba rẹ̀ han àwọn èèyàn aláìpé. (Jòh. 8:28) [May 20, w11 4/1 ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 3]

4. Kí la rí kọ́ lára Jésù nígbà tó “bẹ̀rẹ̀ sí da omijé” lẹ́yìn ikú Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀? (Jòh. 11:35) [May 20, w08 5/1 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 3 àti 4]

5. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ lára Jésù bó ṣe wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (Jòh. 13:4, 5) [May 27, w99 3/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1]

6. Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe lè darí wa síbi tó tọ́? (Jòh. 14:26) [May 27, w11 12/15 ojú ìwé 14 àti 15 ìpínrọ̀ 9]

7. Kí ni “ìwọ̀nyí,” tó wà nínú Jòhánù 21:15 túmọ̀ sí, ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́? [June 3, w08 4/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 11]

8. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 2:44-47 àti Ìṣe 4:34, 35, àpẹẹrẹ wo ló yẹ kí àwa Kristẹni máa tẹ̀ lé? [June 10, w08 5/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 5]

9. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 7:59, ṣé Jésù ni Sítéfánù ń gbàdúrà sí? [June 17, w08 5/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2]

10. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Bánábà? Èrè wo ló sì wà nínú ká ṣe bẹ́ẹ̀? (Ìṣe 9:26, 27) [June 24, bt òjú ìwé 65 ìpínrọ̀ 19]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́