Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 1
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 1
Orin 69 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 11 ìpínrọ̀ 9 sí 14 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìṣe 11-14 (10 min.)
No. 1: Ìṣe 11:1-18 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Iṣẹ́ Ìwàásù Ń Jẹ́ Ká Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀bi Ẹ̀jẹ̀—td 20D (5 min.)
No. 3: Àwọn Wo Gan-an Ni Ọ̀rẹ́ Rẹ?—Sm. 119:63 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù July. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ July, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! July–August 2013. Tí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ọ̀kan lára ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Lúùkù 12:16-31. Ẹ jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni.
Orin 35 àti Àdúrà