Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 15
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 15
Orin 48 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 12 ìpínrọ̀ 1 sí 7 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìṣe 18-21 (10 min.)
No. 1: Ìṣe 20:17-38 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Bá A Tiẹ̀ Ń Bọlá fún Èèyàn, Ọlọ́run Nìkan Ló Yẹ Ká Sìn—td 22B (5 min.)
No. 3: Báwo La Ṣe Lè Máa Gbé Èrò Inú Wa Ka Ẹ̀mí?—Róòmù 8:6 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Jẹ́ Kí Òtítọ́ Dé Ọkàn Àwọn Tí Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́. (Lúùkù 24:32) Ìjíròrò tó dá lórí àwọn ìbéèrè yìí: (1) Tó o bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kó o tẹnu mọ́ (a) ọgbọ́n àti ìfẹ́ Jèhófà? (b) ìdí tó fi yẹ ká máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò? (d) ìdí tó fi yẹ ká máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà ká tó ṣe ìpinnu? (2) Báwo ni àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí ṣe lè jẹ́ kó o mọ̀ bóyá òtítọ́ ń wọ akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́kàn? (a) Ǹjẹ́ o rò pé àlàyé yìí bọ́gbọ́n mu? (b) Ǹjẹ́ o rò pé àlàyé yìí fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa? (d) Àǹfààní wo lo rò pé a máa ní tá a bá fi ìlànà yìí sílò?
20 min: “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́kùnrin, Ǹjẹ́ Ẹ Ṣe Tán Láti Di Ìránṣẹ́ Tàbí Alàgbà?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó sapá kó lè kúnjú ìwọ̀n fún iṣẹ́ nínú ìjọ nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. Kó tó di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, iṣẹ́ wo ló máa ń ṣe nínú ìjọ, báwo sì ni wọ́n ṣe dá a lẹ́kọ̀ọ́? Báwo ni àwọn ará nínú ìjọ ṣe ràn án lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? Àwọn ìbùkún wo ló ti rí nínú bó ṣe sapá láti kúnjú ìwọ̀n fún iṣẹ́ nínú ìjọ?
Orin 85 àti Àdúrà