Báwo Lo Ṣe Máa Lo Àkókò Ọlidé Tó Ń Bọ̀?
Ó dára gan-an ká kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ní àkókò ọlidé ìjọba àti tí ẹ̀sìn torí pé ọ̀pọ̀ ni kì í lọ síbi iṣẹ́ lákòókò yẹn tí wọ́n sì máa ń wà nílé. À ń rọ àwọn ìjọ pé kí wọ́n máa ṣètò lákànṣe láti wàásù láwọn àkókò ọlidé. Tó bá jẹ́ pé lákòókò ọlidé, ó máa pẹ́ díẹ̀ kí ọ̀pọ̀ àwọn tẹ́ ẹ fẹ́ lọ wàásù fún tó jí láàárọ̀, ó máa dáa tẹ́ ẹ bá yí àkókò tẹ́ ẹ̀ ń pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá pa dà. Ẹ lè ṣe ìfilọ̀ ètò àkànṣe tí ìjọ ṣe fún wíwàásù lákòókò ọlidé nígbà Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, kí ẹ sì rọ gbogbo akéde pé kí wọ́n kópa níbẹ̀. A mọ̀ pé, àkókò ọlidé ni àwa náà máa ń ráyè sinmi, àkókò yẹn náà la sì máa fi ń bójú tó àwọn ọ̀ràn ara ẹni míì. Àmọ́, ṣé a lè lo apá kan ọjọ́ náà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Ìgbà yẹn la máa rí i bí ara á ṣe tù wá pé a kópa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run.—Mát. 11:29, 30.