Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 4
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 4
Orin 116 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jl Ẹ̀kọ́ 3 sí 4 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Títù 1-3–Fílémónì 1-25(10 min.)
No. 1: Títù 2:1-15 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Ọjọ́ Ìṣẹ̀dá Kì Í Ṣe Ọjọ́ Oníwákàtí Mẹ́rìnlélógún—td 29B (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Tẹ́tí sí “Àwọn Ìtàn Èké”—1 Tím. 1:3, 4; 2 Tím. 4:3, 4 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù November. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan sọ ìdí táwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé ìròyìn wa ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ November 1, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! November–December 2013. Bí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ọ̀kan lára ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Sa Agbára. (Héb. 4:12) Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Ọdọọdún Wa 2013, ojú ìwé 57, ìpínrọ̀ 1, sí ojú ìwé 60, ìpínrọ̀ 1. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
Orin 114 àti Àdúrà