Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! November àti December: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú mìíràn tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. January: Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! tàbí èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó bá wà lọ́wọ́.
◼ Ẹ lè ṣe àyípadà sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú àpéjọ àgbègbè yín kẹ́ ẹ lè fi jíròrò àwọn ìmọ̀ràn àtàwọn ìránnilétí fún àpéjọ àgbègbè tá a gbé yẹ̀ wò nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù August. Tó bá wá di oṣù kan tàbí méjì lẹ́yìn àpéjọ àgbègbè yín, ẹ lè lo apá tó wà fún ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ láti fi jíròrò àwọn ohun táwọn ará ti rí i pé o wúlò fún àwọn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lára àwọn ohun tẹ́ ẹ gbọ́ ní àpéjọ àgbègbè.