Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù November
“Mo fẹ́ mọ èrò rẹ nípa ìbéèrè yìí: Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá mọ̀ pé wọ́n ti pa irọ́ fún ẹ nípa Ọlọ́run? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé tó wúni lórí nípa kókó yìí.” Lẹ́yìn náà, fún onílé ní Ilé Ìṣọ́ November 1, kí ẹ sì jọ jíròrò èyíkéyìí lára àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé kẹfà. Ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Fún un ní Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, kí o sì ṣètò láti pa dà wá kí ẹ lè máa bá ọ̀rọ̀ yín lọ. Ó sábà máa ń dáa pé ká bi onílé ní ìbéèrè kan tí yóò máa ronú lé lórí di ìgbà tá a fi máa pa dà wá.
Ilé Ìṣọ́ November 1
“Irọ́ wo lo rò pé ó burú jù lọ tí wọ́n pa mọ́ Ọlọ́run? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ òun kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé òun. [Ka Aísáyà 41:13.] Ìwé ìròyìn yìí tú àṣírí àwọn irọ́ mẹ́ta tí wọ́n sábà máa ń pa mọ́ Ọlọ́run tó sì ti mú kó ṣòro fún àwọn kan láti sún mọ́ ọn.”
Ji! November–December
“Mo fẹ́ mọ èrò rẹ nípa ìbéèrè yìí: Ǹjẹ́ èèyàn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ lè ní ìtẹ́lọ́rùn? [Jẹ́ kó fèsì.] Jẹ́ ká gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ. [Ka 1 Tímótì 6:8.] Ìwé ìròyìn yìí máa jẹ́ ká mọ ojú tó yẹ ká fi máa wo nǹkan ìní, ó sì jíròrò àwọn nǹkan pàtàkì mẹ́ta tí owó kò lè rà.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 12 hàn án.