Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù November
“Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè sí ìbéèrè pàtàkì yìí. [Ka ìbéèrè àkọ́kọ́ tó wà lẹ́yìn Ilé Ìṣọ́ November 1.] Kí lèrò yín nípa rẹ̀? [Ka ìpínrọ̀ méjì tó wà lábẹ́ ìbéèrè náà àti ó kéré tán ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀.] Ṣé mo lè pa dà wá ká lè jíròrò ìdí tí Jésù fi jí àwọn èèyàn náà dìde àti àǹfààní tí èyí máa ṣe fún wa?”
Ilé Ìṣọ́ November 1
“Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tó fà á tí àwọn nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀ láyé? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ nínú Ìṣípayá 12:9. [Kà á.] Àmọ́ ṣá o, ẹsẹ 12 jẹ́ ká mọ̀ pé ìrètí ṣì wà. [Kà Ìṣípayá 12:12.] Ipa búburú tí Sátánì ní lórí ayé máa dópin láìpẹ́. Àpilẹ̀kọ yìí tó ní àkòrí náà, ‘Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Bẹ̀rù Sátánì?’ sọ bí a ṣe lè dáàbò bo ara wa ní báyìí kí Sátánì má bàa nípa lórí wa àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Sátánì lọ́jọ́ iwájú. Ìwé ìròyìn tiyín rèé.”
Ji! November–December
“À ń ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn láti dáhùn ìbéèrè yìí. [Fi àkòrí iwájú ìwé ìròyìn Jí! hàn án.] Ǹjẹ́ o rò pé ó dìgbà téèyàn bá di ọlọ́rọ̀ kó tó lè ní ojúlówó àṣeyọrí? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ bí a ṣe lè fi ojú tó tọ́ wo àwọn nǹkan tara. [Ka Lúùkù 12:15.] Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ, kò sí ẹni tí kò lè ní ojúlówó àṣeyọrí. Ìwé ìròyìn yìí á jẹ́ kẹ́ ẹ mọ púpọ̀ sí i.”