Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù April
“À ń gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n máa ka Bíbélì. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń rò pé ohun tó wà nínú Bíbélì kò lè yé àwọn. Ṣé ohun tí ìwọ náà rò nìyẹn? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ohun tí ìwé yìí sọ.” Fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ April 1 han onílé, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àlàyé tó wà lábẹ́ ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, ó kéré tán. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ April 1
“Kò sẹ́ni tí kò níṣòro láyé tá a wà yìí. Èyí ti mú kí nǹkan tojú sú àwọn kan tí wọ́n sì wá ń rò ó pé ìgbésí ayé àwa ẹ̀dá kò ní ìtumọ̀ kankan. Kí lo rò pé kì í jẹ́ káwọn èèyàn láyọ̀ tó bí wọ́n ṣe ń fẹ́ láyé tá a wà yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì ṣèlérí pé Ọlọ́run máa tó fòpin sí gbogbo ìṣòro wa láìpẹ́. [Ka Ìṣípayá 21:4.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn ìlérí Ọlọ́run tó máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú àti bá a ṣe lè ní ayọ̀ láyé tá a wà yìí.”
Jí! March–April
“Tọkọtaya máa láyọ̀ gan-an táwọn méjèèjì bá mọwọ́ ara wọn. Àmọ́ tí ìṣòro bá wà láàárín wọn, ó lè mú kí wọ́n máa bára wọn jiyàn. Ǹjẹ́ o rò pé ìmọ̀ràn inú Bíbélì lè ràn wọ́n lọ́wọ́? [Ka Òwe 29:11. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó fèsì.] Kì í rọrùn fún tọkọtaya tó ń bára wọn jiyàn láti gbé pọ̀ ní àlàáfíà. Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 4 nínú ìwé yìí ṣàlàyé ohun tí àwọn tọkọtaya lè ṣe láti yanjú ìṣòro wọn, tí wọn ò sì ní máa bára wọn jiyàn.”