Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù November
“Ǹjẹ́ o ronú pé àwọn èèyàn tó ń sapá láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run ló máa ń láyọ̀ jù? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn kókó kan tó fani mọ́ra.” Mú Ilé Ìṣọ́ November 1 fún un, kẹ́ ẹ sì jọ ka àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìsọ̀rí tó wà lójú ìwé 16 àti 17, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Ó kéré tán, kẹ́ ẹ ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Béèrè bóyá ó máa fẹ́ láti gba ìwé náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ November 1
“Àwọn kan gbà pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ kò bóde mu mọ́ àti pé kì í jẹ́ kéèyàn ṣe bó ṣe fẹ́. Àwọn míì fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ. Kí lèrò rẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ nípa ibi tí àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì ti wá. [Ka 2 Tímótì 3:16.] Ìwé ìròyìn sọ bí Bíbélì ṣe dáhùn ìbéèrè mẹ́wàá táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa ìbálòpọ̀. Ó tún sọ bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe ń ṣe wá láǹfààní.”
Ji! October–December
“Ǹjẹ́ ohun kan wà téèyàn lè ṣe láti dènà jàǹbá ọkọ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Róòmù 13:1.] Lára ohun tá a lè ṣe láti pa òfin yìí mọ́ ni pé, ká máa pa òfin ìrìnnà mọ́, ká máa lo bẹ́líìtì ààbò, ká má ṣe máa ka ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sórí fóònù tàbí ká máa fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù nígbà tá a bá ń wa ọkọ̀, ká máa tún ọkọ̀ wa ṣe, ká má sì ṣe máa wa ọkọ̀ lẹ́yìn tá a bá ti mu ọtí. Àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 26 jẹ́ ká mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn kókó yìí.”