Bó O Ṣe Lè Dènà Ìjàǹbá Ọkọ̀
TÁYÀ ọkọ̀ fọ́, àwọn ọkọ̀ forí sọ ara wọn, gíláàsì ọkọ̀ fọ́ yángá, àwọn èèyàn ń kígbe . . . Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tó bá ti ní ìjàǹbá ọkọ́ rí gbà pé irú àwọn ìró yìí ni èèyàn máa ń gbọ́ ní irú àkókò bẹ́ẹ̀. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé, kárí ayé, “tá a bá fojú bù ú, àwọn èèyàn tí ó tó mílíọ̀nù kan àbọ̀ ló ń kú lọ́dọọdún nínú ìjàǹbá ọkọ̀, nígbà tí iye èèyàn tó ń fara pa tó àádọ́ta [50] mílíọ̀nù.”
Síbẹ̀, tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà fún ààbò, tó o sì ń lo ọgbọ́n, wàá lè dènà ọ̀pọ̀ jàǹbá ọkọ̀. Jẹ́ ká wo bá a ṣe lè ṣe é.
Sáré Níwọ̀n, Lo Bẹ́líìtì Ààbò, Má Ṣe Máa Fi Ọ̀rọ̀ Ránṣẹ́ Lórí Fóònù
Ní àwọn òpópónà kan, ó lè dà bíi pé ìwọ̀n eré téèyàn lè fi ọkọ̀ sá ti kéré jù. Àmọ́, téèyàn bá sáré ju bó ṣe yẹ lọ, kì í fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ nínú ìgbà tó máa dé ibi tó ń lọ. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ ń wa ọkọ̀ lọ síbi tó jìnnà tó ọgọ́rin [80] kìlómítà. Ọ̀rẹ́ rẹ ń wakọ̀ tirẹ̀ lọ ní ìwọ̀n kìlómítà mẹ́rìnlélọ́gọ́rùn-ún láàárín wákàtí kan [104km/h]. Ṣùgbọ́n ìwọ ń sáré ní ìwọ̀n kìlómítà mọ́kàndínláàádóje láàárín wákàtí kan [129km/h] torí pé o fẹ́ tètè débi tí ò ń lọ, gbogbo àkókò tí o máa fi ṣáájú ẹni yẹn dé ibi tí ẹ̀ ń lọ kò lè tó ìṣẹ́jú mẹ́sàn-án. Ṣé ìwọ̀nba àkókò yẹn wá tó ohun tó o lè torí rẹ̀ fi ẹ̀mí ara rẹ wewu nínú jàǹbá ọkọ̀?
Bẹ́líìtì ààbò máa ń dáàbò bo ni. Ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ìjọba kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, àwọn tí bẹ́líìtì ààbò gba ẹ̀mí wọn là lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, láàárín ọdún 2005 sí 2009, ju ẹgbẹ̀rún méjìléláàádọ́rin [72,000] lọ. Ǹjẹ́ àpò afẹ́fẹ́, ìyẹn air bag lè ṣe iṣẹ́ tí bẹ́líìtì ààbò máa ń ṣe? Rárá o. Àpò afẹ́fẹ́ àti bẹ́líìtì ààbò ló máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ fún ààbò nígbà tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀. Tí o kò bá lo bẹ́líìtì ààbò, àpò atẹ́gùn yẹn kò ní ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, ìyẹn sì léwu gan-an. Torí náà, jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa lo bẹ́líìtì ààbò, kó o sì rí i pé àwọn tó wà nínú ọkọ rẹ náà ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun míì tún rèé: Má ṣe ka ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí ẹ lórí fóònù, má sì ṣe fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù nígbà tó o bá ń wakọ̀.
Ojú Ọ̀nà àti Àbójútó Ọkọ̀
Táyà ọkọ̀ kì í di ilẹ̀ mú dáadáa láwọn ọ̀nà tí omi, eruku, iyẹ̀pẹ̀ tàbí òkúta bá wà. Bí o kò bá sáré ní irú àwọn ọ̀nà bí èyí, táyà ọkọ̀ rẹ kò ní yọ̀ nígbà tó o bá tẹ ìjánu ọkọ̀. Bó bá jẹ́ pé yìnyín sábà máa ń pọ̀ lójú ọ̀nà tó o ti máa ń wakọ̀, á dáa kó o wá bí wàá ṣe ra táyà tí wọ́n fi máa ń wakọ̀ lórí yìnyín nítorí ìgbà òtútù. Irú àwọn táyà yìí máa ń di ilẹ̀ mú dáadáa.
Àwọn ọ̀nà tó jẹ́ ìkòríta máa ń léwu fún gbogbo awakọ̀. Ògbógi kan dábàá pé: Bí iná tó ń darí ọkọ̀ lójú pópó bá tan àwọ̀ ewéko, ṣe sùúrù díẹ̀ kó o tó wọ ìkòríta. Tó o bá dúró díẹ̀, èyí kò ní jẹ́ kí ọkọ̀ tó ń sáré bọ̀ tí kò dúró nígbà tí iná pupa tan kọlù ẹ́.
Mímú kí ọkọ̀ rẹ wà ní ipò tó dára jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan láti gbà yẹra fún jàǹbá ọkọ̀. Ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tí ìjánu ọkọ̀ rẹ kò bá ṣiṣẹ́ nígbà tí ò ń wakọ̀. Ohun táwọn awakọ̀ kan máa ń ṣe láti dènà ìṣòrò ọkọ̀ ni pé, wọ́n máa ń ṣètò bí mẹkáníìkì kan tó mọṣẹ́ dáadáa á ṣe máa ṣe àbójútó ọkọ̀ wọn déédéé. Bákan náà, àwọn awakọ̀ kan máa ń yàn láti ṣe àwọn àbójútó kan lára ọkọ̀ wọn fúnra wọn. Ọ̀nà yòówù kó o máa gbà ṣe é, ṣáà rí i dájú pé o ń ṣe àyẹ̀wò àti àtúnṣe ọkọ̀ rẹ bó ṣe yẹ.
Má Ṣe Wakọ̀ Tó O Bá Mutí
Àwọn awakọ̀ tí wọ́n mọ ọkọ̀ wà dáadáa tí wọ́n sì máa ń wakọ̀ pẹ̀lú ìṣọ́ra pàápàá lè fi ẹ̀mí ara wọn wewu tí wọ́n bá wakọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti mu ọtí. Lọ́dún 2008 lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn tí jàǹbá ọkọ̀ pa lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógójì [37,000]. Nǹkan bí ìdá mẹ́tà nínú àwọn tó kú yìí ló jẹ́ pé àwọn awakọ̀ tó mutí ló fa jàǹbá ọkọ̀ náà. Kódà, bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ọtí díẹ̀ lo mu pàápàá, èyí lè mú kó o má lè wakọ̀ dáadáa. Àwọn kan ti pinnu pé àwọn kò ní máa mu ọtí rárá táwọn bá máa wakọ̀.
Máa tẹ̀ lé àwọn òfin ìrìnnà, máa wọ bẹ́líìtì ààbò, máa ṣe àbójútó àti àtúnṣe ọkọ̀ rẹ, má sì ṣe wakọ̀ lẹ́yìn tó o bá ti mutí. Àwọn nǹkan wọ̀nyí lè gba ìwọ àtàwọn tó o bá gbé lọ́wọ́ ikú òjijì. Àwọn àbá yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè dènà jàǹbá ọkọ̀. Ṣùgbọ́n, tí àwọn àbá yìí bá máa ṣe ẹ́ láǹfààní, àfi kó o máa tẹ̀ lé wọn.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
MÁ ṢE WAKỌ̀ TÍ OORUN BÁ Ń KÙN Ẹ́
“Ohun kan táwọn èèyàn gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn ni pé bí oorun bá ń kun èèyàn nígbà tó ń wa ọkọ̀, onítọ̀hún kò yàtọ̀ sí ẹni tó ti mutí tó sì ń wakọ̀.” Òṣìṣẹ́ àjọ kan tí wọ́n ń pè ní National Sleep Foundation lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó sì jẹ́ ká mọ ewu tó wà nínú kéèyàn máa wa ọkọ̀ nígbà tí oorun bá ń kùn ún. Àwọn àmì tá a kọ síbí yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ pé ó léwu láti wa ọkọ tí èyíkéyìí lára wọn bá ń ṣe ẹ́:a
● Tó bá ṣòro fún ẹ láti pọkàn pọ̀, tó o bá ń ṣẹ́jú léraléra, tàbí tí ojú rẹ bá wúwo
● Tó bá ṣòro fún ẹ láti gbórí sókè
● Tó o bá ń yán léraléra
● Tó bá ṣòro fún ẹ láti rántí ibùsọ̀ mélòó kan tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ rìn
● Tó o bá kọjá ibi tó yẹ kó o ti yà tàbí tí o kò rí àwọn àmì ojú pópó
● Tó o bá ń yà bàrà kúrò lójú ọ̀nà rẹ, tó o bá ń fi imú ọkọ̀ tìrẹ gbá ọkọ̀ tó wà níwájú rẹ tàbí tó o yà kúrò lójú pópó
Bí èyíkéyìí bá ń ṣe ẹ́ lára àwọn àmì tó wà níbí yìí, jẹ́ kí ẹlòmíì wa ọkọ̀ tàbí kó páàkì síbi tí kò léwu kó o sì sùn díẹ̀. Ó sàn kó o pẹ́ débi tí ò ń lọ ju pé kó o fi ẹ̀mí ara rẹ àtàwọn míì sínú ewu.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àjọ National Sleep Foundation ló ṣètò àwọn ìsọfúnni yìí.