Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Àjọ tó Ń Bójú Tó Ààbò Ojú Pópó ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà (NHTSA) sọ, jàǹbá ọkọ̀ lohun tó ń fa ikú àwọn ọmọ tó wà láàárín ọdún márùn-ún sí mẹ́rìnlá jù lọ. Àjọ NHTSA sọ pé: “Ohun tó ju ìdajì àwọn ọmọ tó ń kú nínú jàǹbá ọkọ̀ ni wọn kì í de bẹ́líìtì ara ìjókòó ọkọ̀ [tó wà fún ìdáàbòbò]. Yàtọ̀ síyẹn, mẹ́rin lára ọmọ márùn-ún ni wọn kì í de bẹ́líìtì ara ìjókòó ọkọ̀ fún dáadáa.”
Àjọ náà fúnni láwọn ọ̀nà ìdáàbòbò bíi mélòó kan àti àwọn ìṣọ́ra tí àwọn tó máa ń gbé àwọn ọmọ sínú ọkọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń wakọ̀ lè lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin yàtọ̀ láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, tí òfin ìpínlẹ̀ kan sì lè yàtọ̀ sí ti òmíràn, síbẹ̀, ó yẹ kí àwọn òbí àti alágbàtọ́ ronú lórí àwọn ìlànà yìí dáadáa. Jọ̀wọ́ ṣàyẹ̀wò àwọn òfin tó wà fún àdúgbò rẹ kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ tó o gbé tira nínú ọkọ̀!
ÀWỌN ÌLÀNÀ FÚN ÌDÁÀBÒBÒ
Ìjókòó ẹ̀yìn nibi tó láàbò jù lọ fún gbogbo ọmọ láti máa jókòó.
1 A ní láti gbé àwọn ọmọ ọwọ́ sínú ìjókòó ìdáàbòbò tó wà fún àwọn ọmọdé èyí tó máa ń kọjú sẹ́yìn ní ìjókòó ẹ̀yìn.
2 A lè gbé ọmọ ọdún kan ó kéré tán tó sì wọn kìlógíráàmù mẹ́sàn-án sínú ìjókòó tó máa ń kọjú síwájú ní ìjóòkó ẹ̀yìn.
3 Tí ọmọ náà bá ti wọn kìlógíráàmù méjìdínlógún, ó lè lo “ìjókòó alágbèéléra inú ọkọ̀,” tí wọ́n á sì fi bẹ́líìtì àdèmọ́tan àti àdèméjìká de ọmọ náà.
4 Tọ́mọ náà bá ti ń lọ sí nǹkan bíi kìlógíráàmù mẹ́rìndínlógójì tó sì ti ga ní ogóje sẹ̀ǹtímítà, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo bẹ́líìtì ààbò táwọn àgbàlagbà ń lò.
ÌṢỌ́RA
Àwọn ọmọdé kò gbọ́dọ̀ jókòó sí ìjókòó iwájú títí dìgbà tí wọ́n á fi pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá ó kéré tán. Àpò alátẹ́gùn tó ń dáàbò bo awakọ̀ bí jàǹbá ọkọ̀ bá ṣẹlẹ̀ tó máa ń wà níwájú ọkọ̀ lè ṣe àkóbá ńlá fún àwọn ọmọ kékeré àti àwọn ọmọ ọwọ́.
Tó bá jẹ́ ìjókòó alágbèéléra inú ọkọ̀ lo lò, bẹ́líìtì àdèmọ́tan nìkan kò tó láti pèsè ààbò tí ìjókòó náà kò bá ní ohun kan tó lè gba ọmọ náà dúró tó bá fì síwájú.
Má ronú pé bẹ́líìtì àdèméjìká nìkan ti tó láti dáàbò bo ọmọ kékeré kan o; tí jàǹbá bá lọ ṣẹlẹ̀, bẹ́líìtì náà lè fún ọmọ náà lọ́rùn, èyí lè ṣe é léṣe gidigidi tàbí kó tiẹ̀ pa á.
Tó o bá ń de ìjókòó ọmọdé mọ́ inú ọkọ̀ tàbí tó o bá ń de ọmọ mọ́nú rẹ̀, tẹ̀ lé ìlànà dáadáa. Gẹ́gẹ́ bí àjọ NHTSA ṣe sọ, “kódà, ìjókòó ‘tí ààbò rẹ̀ dájú jù lọ’ lè máà dáàbò bo ọmọ rẹ tí o kò bá lò ó lọ́nà tó yẹ.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Láti mú kí ìjókòó ìdáàbòbò tó wà fún ọmọdé wà ní sẹpẹ́, de bẹ́líìtì ara ìjókòó ọkọ̀ dáadáa