ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 10/8 ojú ìwé 22-25
  • Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ Kí Jàǹbá Má Bàa Ṣe É

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ Kí Jàǹbá Má Bàa Ṣe É
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nílé
  • Níta
  • Lójú Títì
  • Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín
    Jí!—2007
  • Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kó Lè Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ikú Fà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ojúṣe Rẹ Gẹ́gẹ́ bí Òbí
    Jí!—2004
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 10/8 ojú ìwé 22-25

Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ Kí Jàǹbá Má Bàa Ṣe É

LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SWEDEN

HANNA, tó kù díẹ̀ kó pé ọmọ ọdún mẹ́ta, wà pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀, Karl-Erik àti Birgitta, bí wọ́n ti ń palẹ̀ ilé aládùúgbò wọn kan tó ṣaláìsí mọ́. Nígbà tó ṣe, Hanna ti yàrá kan jáde wá tòun ti ìgò oògùn kan lọ́wọ́ rẹ̀. Ó ti kó lára oògùn náà mì. Ṣe ni àyà Birgitta já pàrà nígbà tó yẹ ìgò náà wò. Ìgò oògùn tí aládùúgbò náà ń lò sí àrùn ọkàn tó ṣe é ni.

Ní kíá mọ́sá, wọ́n gbé Hanna lọ sí ọsibítù, ó sì wà níbẹ̀ mọ́jú fún àkànṣe ìtọ́jú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye oògùn tó kó mì pọ̀ débi pé ì bá máà gbádùn fún gbogbo ọjọ́ ayé ẹ̀, a dúpẹ́ pé aburú kan ò ṣẹlẹ̀ sí i. Èé ṣe? Torí pé kò pẹ́ tó mu oríṣi ògì kan tán, tó lọ kó oògùn wọ̀nyẹn mì. Ògì náà ti fà lára májèlé náà mu, ó sì wá bi ògì náà.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hanna yìí kì í ṣe tuntun. Lójoojúmọ́, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ kárí ayé ló máa ń kó sínú wàhálà tó ń sọ ọ́ di túláàsì láti lọ rí dókítà tàbí láti lọ sí ọsibítù. Lọ́dọọdún, ọmọ kan nínú mẹ́jọ ní Sweden ló máa ń gbàtọ́jú lẹ́yìn jàǹbá. Fún ìdí yìí, bí o bá jẹ́ òbí, irú nǹkan yìí lè ṣẹlẹ̀ dáadáa sọ́mọ tìrẹ.

Kò ṣàjèjì rárá pé kí ọmọdé ṣèṣe láyìíká tó mọ̀ dunjú, bóyá nílé tàbí lágbègbè ilé. Irú èṣe náà máa ń yàtọ̀ bí wọ́n ti ń dàgbà sí i. Ó rọrùn kí ìkókó yí lulẹ̀ látorí àkéte, tàbí kóúnjẹ sápá a lórí, tàbí kí nǹkan há a lọ́fun. Àwọn ọmọ kéékèèké máa ń ṣubú nígbà tí wọ́n bá ń gun nǹkan kiri tàbí kí nǹkan jó wọn lọ́wọ́ níbi tí wọ́n ti ń táwọ́ sí gbogbo nǹkan tọ́wọ́ wọn lè bá, tàbí kí wọ́n mu májèlé nígbà tí wọ́n bá ń tọ́ gbogbo nǹkan tọ́wọ́ wọ́n bá tẹ̀ wò. Àwọn ọmọ tó ti tó iléèwé lọ sábà máa ń ṣèṣe nínú jàǹbá mọ́tò tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré níta.

Ọ̀pọ̀ lára jàǹbá wọ̀nyí ló ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Tóo bá fojú sílẹ̀ dáadáa, tóo sì mòye bí ọmọ rẹ ṣe dàgbà tó, o lè gbà á lọ́wọ́ èṣe tàbí jàǹbá burúkú pàápàá. Ètò kan tó ti wà ní ilẹ̀ Sweden láti 1954 fún ààbò àwọn ọmọdé ti fẹ̀rí ti èyí lẹ́yìn. Kó tó di ọdún yẹn, ó ju àádọ́ta lé nírínwó ọmọdé tó ń kú lọ́dọọdún nínú jàǹbá. Ní báyìí, iye tí ń kú lọ́dọọdún kò ju àádọ́rin mọ́.

Nílé

Kerstin Bäckström, afìṣemọ̀rònú ọmọdé sọ pé: “Kò sí bóo ṣe lè kọ́ ọmọ ọdún kan, ọmọ ọdún méjì, tàbí ọmọ ọdún mẹ́ta pé kó yẹra fún ewu, kí o sì retí pé kò ní gbàgbé.” Fún ìdí yìí, ojúṣe ìwọ tóo jẹ́ òbí—tàbí tàwọn àgbàlagbà mí-ìn tọ́mọ máa ń lò sọ́dọ̀ wọn—ni láti ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti yẹra fún jàǹbá.

Ká tibi pẹlẹbẹ mọ́ọ̀lẹ̀ jẹ, wò yí ká ilé rẹ. Lo àwọn kókó tó wà nínú àpótí tí o ń wò lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan yìí. Ó lè jẹ́ pé gbogbo orílẹ̀-èdè kọ́ ló ṣètò oríṣi ààbò kan tàbí kó jẹ́ pé ó wọ́nwó. Síbẹ̀, pẹ̀lú làákàyè àti ọgbọ́n inú wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, o lè ronú kan ohun tí yóò gbéṣẹ́ nínú ọ̀ràn tìrẹ.

Fún àpẹẹrẹ, bó bá ṣe pé ìkọ́ oníhò ló wà lára ilẹ̀kùn kọ́bọ́ọ̀dù inú kíṣìnnì rẹ, o lè kan igi dí i. O lè ṣe ohun kan náà sí ilẹ̀kùn àdògán oníná tí wọ́n fi ń yan nǹkan. Á ṣòro kí àwọn àpò oní-náílọ́ọ̀nù tó pani lára tí o bá ta wọ́n ní kókó kí o tó tọ́jú wọn.

O tún lè ronú àwọn ọ̀nà mí-ìn tó rọrùn láti fi yẹra fún jàǹbá nínú ilé àti láyìíká rẹ, o sì lè ṣàlàyé nǹkan wọ̀nyí fáwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ tó ní àwọn ọmọ kéékèèké.

Níta

Ṣàyẹ̀wò àwọn ibi tọ́mọ rẹ ti ń ṣeré. Ọ̀pọ̀ jù lọ èṣe tó ń ṣe àwọn ọmọdé tọ́jọ́ orí wọn lé lọ́dún mẹ́rin máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré níta. Wọ́n máa ń ṣubú ṣe ara wọn léṣe, tàbí kí wọ́n ṣubú lórí kẹ̀kẹ́. Jàǹbá burúkú tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ níta sáwọn ọmọdé tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ta sí méje ni jàǹbá ohun ìrìnnà àti kíkó sómi.

Nígbà tóo bá lọ wo ibi ìṣeré wọn, rí i bóyá àwọn ohun ìṣeré tó wà níbẹ̀ ń ṣiṣẹ́ dáadáa, kí wọ́n má bàa ṣe ọmọ léṣe nígbà tó bá ń lò wọ́n. Ṣé àwọn nǹkan bíi yanrìn rírọ̀ tàbí fùlùfúlù ló wà nílẹ̀ ibi táwọn ọmọ ti ń ṣe eré jangirọ́fà, tàbí eré mo-le-gòkè-mo-le-sọ̀, tàbí irú àwọn eré bẹ́ẹ̀, kí ọmọ má bàa ṣe ara rẹ̀ léṣe tó bá ṣubú?

Ǹjẹ́ adágún omi tàbí odò wà nítòsí ilé ẹ? Kò dìgbà tí omi jìn kó tó lè ṣekú pa ọmọ ọdún kan tàbí méjì. Bäckström afìṣemọ̀rònú ọmọdé sọ pé: “Tọ́mọdé bá ṣubú ní ìdojúbolẹ̀ sínú omi, kì í mọ nǹkan tí wọ́n ń pè ní òkè àtìsàlẹ̀ mọ́. Ọmọ náà á dìde tì ṣáá ni.”

Nítorí náà, ìlànà tó ṣe kókó jù lọ rèé: O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọmọ ọdún kan sí mẹ́ta máa dá ṣeré níta láìsí àgbàlagbà nítòsí. Bí odò bá wà ládùúgbò, jẹ́ kí ọmọ dàgbà tó kóo tó jẹ́ kó máa lọ dá ṣeré níta.

Lójú Títì

Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀ràn rí bí ilé rẹ bá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì. Bäckström sọ pé: “Ìsọfúnni kan ṣoṣo tó ṣe pàtó nìkan ló lè yé ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iléèwé. Bẹ́ẹ̀ rèé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà lójú títì tó jẹ́ pé ó díjú gan-an, àfi téèyàn bá lè fòye gbé e.” Má ṣe jẹ́ kí ọmọ rẹ dá sọdá títì kí ó tó tó iléèwé lọ. Àwọn ògbógi kò gbà pé ọmọdé tí kò tó ọmọ ọdún méjìlá, ó kéré tán, lè máa dá gun kẹ̀kẹ́ lójú títì tí ohun ìrìnnà pọ̀ sí.

Kọ́ ọmọ rẹ bí yóò ṣe máa dé akoto tó bá ń gun kẹ̀kẹ́ tàbí ẹṣin, tàbí nígbà tó bá wọ àwọn bàtà onítáyà tó fi ń ṣeré kiri. Wàhálà ni o, téèyàn bá forí ṣèṣe, ọgbẹ́ tó ṣòroó wò ni—èèyàn tiẹ̀ lè gbabẹ̀ kú! Nílé ìwòsàn àwọn ọmọdé kan, ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n ń tọ́jú níbẹ̀ lẹ́yìn jàǹbá orí kẹ̀kẹ́ ló fi orí àti ojú ṣèṣe, ṣùgbọ́n àwọn tó lo akoto kò forí ṣèṣe púpọ̀.

Pẹ̀lúpẹ̀lù, rí i dájú pé ẹ̀mí ọmọ rẹ dè nígbà tó bá wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ní òfin tó sọ pé dandan ni kí àwọn ọmọdé jókòó sórí àkànṣe ìjókòó tó wà fáàbò ọmọdé. Èyí ti jẹ́ kí iye àwọn ọmọ tí ń ṣèṣe tàbí tí ń kú nínú jàǹbá ọkọ̀ dín kù gan-an. Bí irú àkànṣe ìjókòó yìí bá wà níbi tóo ń gbé, lílò ó lè gba ẹ̀mí là. Àmọ́, rí i dájú pé ó jẹ́ èyí tíjọba fọwọ́ sí. Ṣàkíyèsí pé ìjókòó àwọn ìkókó tún yàtọ̀ sí tàwọn ọmọdé tọ́jọ́ orí wọ́n bẹ̀rẹ̀ láti nǹkan bí ọdún mẹ́ta sókè.

Ẹ̀bùn àtàtà látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọmọ wa jẹ́, ẹni ìkẹ́ ẹni ìgẹ̀ sì ni wọ́n jẹ́ lójú wa. (Sáàmù 127:4) Gẹ́gẹ́ bí òbí rere, Karl-Erik àti Birgitta kò fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ọ̀ràn dídáàbòbo àwọn ọmọ wọn rí—ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Hanna àti lẹ́yìn rẹ̀. Karl-Erik sọ pé: “Ṣùgbọ́n a ti túnra mú lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn.” Birgitta wá dé e ládé, ó ní: “A ti ní àwọn ọmọ ọmọ báyìí, a sì máa ń rí i dájú pé ọwọ́ wọn kò lè tó ibi tí a ti àwọn oògùn wa mọ́.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

Ààbò Nínú Ilé Rẹ

• Oògùn: Má ṣe fi í síbi tọ́wọ́ ọmọdé yóò ti tó o, tì í mọ́nú kọ́bọ́ọ̀dù. Èyí ò yọ oògùn kankan sílẹ̀ o, títí kan egbòogi àti àgbo. Bákan náà, sọ fún àlejò tó bá máa sùn mọ́jú pé kí wọ́n tọ́jú oògùn wọn.

• Àwọn kẹ́míkà táa ń lò nínú ilé: Kó wọn sínú àwọn kọ́bọ́ọ̀dù tó ní kọ́kọ́rọ́. Má dà á sínú ike mí-ìn, kí a má bàa ṣì í mú. Máa ṣọ́ ọ lójú méjèèjì bóo bá ń lò ó lọ́wọ́, kí o sì máa kó o kúrò nílẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ́jú kan ṣoṣo lo fi máa kúrò ní yàrá. O ò gbọ́dọ̀ fi ọṣẹ tóo lò kù sílẹ̀ẹ́lẹ̀.

• Sítóòfù: Máa rí i pé iga páànù tóo gbé ka sítóòfù kò yọ gọngọ síta. Rí i dájú pé ìkòkò jókòó dáadáa sórí iná. Rí i dájú pé o gbé irin tó ń jẹ́ kí ìkòkò jókòó dáadáa lérí sítóòfù ẹ kó má bàa yí ṣubú níbi tóo gbé e sí, kódà tí ọmọ bá tilẹ̀ mi ibi tóo gbé e lé jìgìjìgì. Ó tún yẹ kí ilẹ̀kùn ara ẹ̀rọ tí o fi ń yan nǹkan ṣe é tì. Ǹjẹ́ ọmọdé lè ráyè tọwọ́ bọná? A jẹ́ pé wàá bo sítóòfù náà débi pé kò ní lè ráyè fọwọ́ síbi tíná wà.

• Àwọn nǹkan èlò ilé tó lè ṣeni léṣe: Ọ̀bẹ, sáàsì, àtàwọn ohun èlò mí-ìn tó lè ṣeni léṣe gbọ́dọ̀ wà nínú kọ́bọ́ọ̀dù tàbí àpótí tó ní kọ́kọ́rọ́ tàbí ìṣíkà, tàbí kí o kó wọn síbi tọ́wọ́ ọmọ ò ti ní lè tó o. Nígbà tóo bá ń lo irú ohun èlò bẹ́ẹ̀, tóo sì fi wọ́n sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan fún sáà kan, má ṣe fi wọ́n sétí tábìlì tàbí káńtà, tí ọwọ́ ọmọ ti lè tó o. Ìṣáná àti àwọn àpò oní-náílọ́ọ̀nù pẹ̀lú lè ṣe àwọn ọmọdé léṣe.

• Àkàsọ̀: Ṣe àwọn ilẹ̀kùn tó ga tó àádọ́rin sẹ̀ǹtímítà, ó kéré tán, sí òkè àtìsàlẹ̀ àkàsọ̀.

• Fèrèsé àti ilẹ̀kùn bákónì: Fi àwọn ìṣíkà tàbí ẹ̀wọ̀n sápá òkè rẹ̀, tàbí àwọn nǹkan mí-ìn tọ́mọdé kò ní mọ̀ ọ́n ṣí, tàbí tí á lè rúnra gba ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kọjá nígbà tẹ́ẹ bá ṣí i kí afẹ́fẹ́ lè ráyè wọlé.

• Ibi ìkówèésí: Bó bá jẹ́ ọmọ tó máa ń fẹ́ gun nǹkan, kó sì máa rọ̀ mọ́ ọn, kan ibi ìkówèésí tàbí àwọn kọ́bọ́ọ̀dù gíga mìíràn mọ́ ara ògiri, kí wọ́n má bàa sojú dé.

• Ihò àti okùn iná mànàmáná: O gbọ́dọ̀ fi nǹkan bo àwọn ojú ihò mànàmáná nígbà tí o ò bá lò wọ́n. Okùn àtùpà oníná àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ tí ń lo iná ni a gbọ́dọ̀ ta sára ògiri tàbí kọ́bọ́ọ̀dù, kí ọmọdé má bàa lè fa àtùpà náà lu ara rẹ̀ lórí. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, gbé irú àtùpà bẹ́ẹ̀ kúrò nílẹ̀. O ò gbọ́dọ̀ fi áyọ́ọ̀nù oníná sílẹ̀ sórí tábìlì ìlọṣọ, má sì jẹ́ kí okùn rẹ̀ rọ̀ dirodiro wálẹ̀.

• Omi gbígbóná: Bó bá jẹ́ ilé tí ẹ̀rọ ti ń se omi gbígbóná fún wíwẹ̀ ni, rí i dájú pé ẹ̀rọ náà kò sè é gbóná ju nǹkan bí ìwọ̀n àádọ́ta Celsius, kí ó má bàa jó ọmọ náà nígbà tó bá ṣí omi sórí.

• Ohun ìṣeré: Kó àwọn ohun ìṣeré tí ẹnu wọn bá mú sọnù. Kó àwọn ohun ìṣeré kéékèèké tàbí àwọn èyí tó ṣeé já sí wẹ́wẹ́ sọnù, torí pé ó lè lọ dí ọ̀nà ọ̀fun ọmọdé tó bá fi sẹ́nu. Ẹyinjú àti imú àwọn bèbí ọmọdé gbọ́dọ̀ wà ní dídè pinpin. Kọ́ àwọn ọmọ tó ti dàgbà pé kí wọ́n máa kó ohun ìṣeré wọn kéékèèké kúrò nílẹ̀ nígbà tí ọmọ bá ń ṣeré kiri ilẹ̀.

• Mindin-mín-ìndìn àti ìpápánu: Má ṣe fi àwọn ìpápánu bí ẹ̀pà tàbí àwọn bíi tìrẹ́bọ̀ síbi tọ́mọdé lè dé. Wọ́n lè lọ há ọmọ lọ́fun.

[Credit Line]

Orísun: Iléeṣẹ́ Ìjọba Tí Ń Bójú Tó Àwọn Ògo-Wẹẹrẹ

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

Bí Jàǹbá Bá Ṣẹlẹ̀

• Jíjẹ májèlé: Bí ọmọ bá mu májèlé, fọ ẹnu rẹ̀ mọ́ tónítóní, kí o sì fún un ní omi tàbí wàrà ife kan tàbí méjì mu. Lẹ́yìn náà, kàn sí dókítà tàbí iléeṣẹ́ tí ń pèsè ìsọfúnni nípa májèlé pé kí wọ́n gbà ẹ́ nímọ̀ràn. Bí nǹkan tó ti dógùn-ún bá ta sọ́mọ lójú, tètè fi omi púpọ̀ ṣan ojú yẹn fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá, ó kéré tán.

• Tí iná bá jóni: Bí kò bá pọ̀, ti ibẹ̀ bọ omi tútù (tí kò tutù jù) fún ogún ìṣẹ́jú, ó kéré tán. Bó bá fẹ̀ ju àtẹ́lẹwọ́ ọmọ náà, tàbí bó bá ṣe pé ojú, tàbí oríkèé, tàbí ìsàlẹ̀ ikùn tàbí abẹ́ ni, tètè gbé ọmọ náà lọ fún ìtọ́jú pàjáwìrì. Dókítà ló yẹ kí ó tọ́jú àwọn egbò tó bá pọ̀ gan-an, tó ti kan ẹran ara.

• Tí nǹkan bá háni lọ́fun: Bí nǹkan kan bá lọ dí ọ̀nà ọ̀fun ọmọ, ọ̀ràn kánjúkánjú gbáà ni, o gbọ́dọ̀ yọ kinní ọ̀hún jáde kíákíá. Ọ̀nà kan tó gbéṣẹ́ tóo lè lò ni kí o bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ikùn ọmọ náà. Bí o ò bá mọ̀ ọ́n ṣe, kàn sí dókítà rẹ kí o lè gba ìsọfúnni púpọ̀ sí i nípa bóo ṣe lè mọ̀ ọ́n ṣe, tàbí kí o lọ síbi tí wọ́n ti ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ nípa jàǹbá ọmọdé tàbí ìtọ́jú pàjáwìrì, níbi tí wọ́n ti lè ṣàlàyé ọ̀nà ìtọ́jú yìí.

[Credit Line]

Orísun: Ẹgbẹ́ Alágbèélébùú Pupa ti Sweden

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Dídé akoto lórí kẹ̀kẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ó wà láàbò lórí ìjókòó inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́